IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 4 January 2025

O ma ṣe! Akọwe funjọba ipinlẹ Ondo ti jade laye


Honourable Temitayo Oluwatuyi, ti gbogbo aye mọ si Tukana ni wọn ti kede pe o jade laye bayii. 


Aarọ ọjọ Satide, ọjọ kẹrin oṣu kin-in-ni ọdun yii la gbọ pe ọkunrin naa ku nileewosan kan. 


Saa akọkọ gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Arakunrin Rotimi Akeredolu ni Oluwatuyi ti kọkọ ṣe akọwe ijọba, oṣu mẹsan pere lo si lo nigba naa. 


Oṣu kin-in-ni ọdun 2024 ni Gomina Lucky Ayedatiwa tun un yan gẹgẹ bii akọwe funjọba ko too di pe o jade laye laarọ oni.

No comments:

Post a Comment