IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 12 January 2025

L'Ọṣun, ọkọ akoyọyọ tẹ ọmọ baba oniburẹdi pa


Irọlẹ ọjọ Satide, ọjọ kọkanla oṣu kin-in-ni ọdun 2025 niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni Marvellous Junction, Ọbaagun nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Ọṣun. 


Gbagede gbọ pe ṣe ni baba oniburẹdi naa ran ọmọ rẹ lati lọọ ra epo bẹntiroolu, o si ku diẹ ko debẹ ni ọkọ akoyọọyọ naa gba a, to si ku loju ẹsẹ. 


Ọna Ikirun ni wọn ni ọkọ naa ti n bọ, to si n lọ si kuari kan to wa lagbegbe ọhun, ere asapajude to n sa la gbọ pe o ṣokunfa iṣẹlẹ naa. 


Bo ṣe pa ọmọdekunrin naa la gbọ pe dẹrẹba akoyọọyọ naa fẹẹ maa sa lọ, ṣugbọn alubami lawọn ọdọ agbegbe naa lu u nigba ti wọn mu un. 


Alukoro ajọ Sifu Difẹnsi l'Ọṣun, Kehinde Adeleke, ṣalaye pe ọpẹlọpẹ awọn agbofinro, ṣe lawọn ọdọ agbegbe ọhun fẹẹ lu dẹrẹba naa pa, wọn ni bi wọn ṣe maa n sare buruku lagbegbe ọhun niyẹn. 


Amọ ṣa, wọn ti fa dẹrẹba naa le awọn ọlọpaa Ifẹlodun lọwọ fun igbesẹ to tọ.

No comments:

Post a Comment