IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 4 January 2025

L'Ọṣun, awọn ọdọ lu Kabiesi lalubami, wọn lo kọja aaye rẹ lọjọọ Jimoh


Awọn ọdọ kan ti inu n bi la gbọ pe wọn pokọ iya fun Ajẹniju ti Halleluyah niluu Ido-Ọṣun, Ọba Yusuff Jelili Ọlaiya, lọjọ Jimoh, ọjọ kẹta oṣu kin-in-ni ọdun yii. 


A gbọ pe ṣe ni Ọba Ọlaiya fi ọkunrin kan, Ahmed Tijani jẹ Imaamu Agba fun Ajẹniju lọsẹ to kọja, nigba ti iyẹn si lọ si mọṣalaaṣi lati kirun Jimoh ni wahala bẹ silẹ. 


Tẹ o ba gbagbe, ni kete ti Olojudo ana, Ọba Aderẹmi Adedapọ, waja ni awọn ọmọbibi ilu naa fẹsun kan Timi Ẹdẹ, Ọba Munirudeen Lawal pe o fẹẹ fi ẹnikan jọba lagbegbe kan to wa lori ilẹ Ido-Ọṣun. 


Wọn kọ oniruuru iwe sileeṣẹ ọlọpaa atijọba ipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn lẹyin o rẹyin, ijọba fun Ọba Ọlaiya ni ọpa aṣẹ ti wọn si sọ ọ di Ajẹniju ti Halleluyah, Ẹdẹ Land, Ẹgbẹdọrẹ, nipinlẹ Ọṣun. 


Latigba naa ni ara ko ti rọ okun, ti ara ko rọ adiyẹ, ohun ti awọn ọmọ Ido Ọṣun n sọ ni pe nigbawo ni ilu Ẹdẹ de abẹ ijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ. 


Amọ ṣa, kayeefi lo tun jẹ bi wọn tun ṣe gbọ pe Ọba Ọlaiya tun fi ẹnikan jẹ Imaamu Agba, lasiko ti iyẹn si fẹẹ kirun Jimoh lawọn kan yari fun un pe ori ilẹ Ido-Ọṣun ni Ajẹniju wa, ṣe ni ko wa ibi to ti fẹẹ kirun lọ. 


Ọrọ yii ni wọn n fa mọ ara wọn lọwọ ti wahala fi bẹ silẹ, wọn da gbogbo mọṣalaaṣi ru, wọn si fọwọ ba kabiesi laafin rẹ.

No comments:

Post a Comment