Ajọ Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ọṣun ti n wa iya to bi ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun kan, Quadija Abimbọla, ẹni ti wọn ri to n rin kaakiri agbegbe Owode-Ẹdẹ.
Alukoro ajọ naa, Kehinde Adeleke, ṣalaye pe aago kan oru ọjọ kọkandinlogun oṣu kin-in-ni ọdun yii lawọn alaanu ri ọmọ naa, ti wọn si mu un lọ si ọfiisi ajọ ọhun.
Quadija ṣalaye pe lati ilu Eko ni iya oun, Aishat Abimbọla, ti mu oun atawọn aburo oun mẹta wa sipinlẹ Ọṣun fun ayẹyẹ ọdun tuntun.
O ni lẹyin ọdun ni iya oun mu oun lọ si ọja Owode-Ẹdẹ pe ki oun lọọ ta ọṣẹ ifọbọ ati pe oun (Iya Quadija) yoo pada wa mu un nirọlẹ, ṣugbọn ti ọmọ yii ko gburo iya rẹ mọ.
Adeleke fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo igbiyanju ajọ naa lati ri iya tabi awọn mọlẹbi Quadija ni ko so eso rere kankan.
Wọn wa n ke si ẹnikẹni to ba mọ bi wọn ṣe le ri awọn mọlẹbi ọmọdebinrin naa lati jade sọ.
No comments:
Post a Comment