Latari bi eto ọrọ-aje ṣe dẹnukọlẹ lorileede Naijiria bayii, Gomina Ademọla Adeleke, ti pinnu lati lo ọgbọn atinuda ti ọpọlọpọ awọn ọdọ ni lasiko yii fun idagbasoke ipinlẹ Ọṣun.
Oludamọran pataki fun Gomina Adeleke, Ọgbẹni Bamikọle Omishore, ti sọ pe idi niyii tijọba fi ṣagbekalẹ eto idanilẹkọọ kan fun awọn ọdọ lati le ṣamulo ọgbọn wọn.
Omishore ṣalaye pe ẹẹdẹgbẹrin ọdọ lo ti forukọ silẹ bayii lati kopa ninu eto naa ti yoo waye laarin ọjọ kejodinlọgbpọn si ọgbọnjọ oṣu kin-in-ni ọdun yii ni ibudo ẹkọṣẹ ọwọ (SDG Skill Acquisition Centre) to wa niluu Iragbiji.
O ni oun to gbe orileede yii de ipo to wa bayii ni bi awọn adari ko ṣe karamasiki ọgbọn atinuda ti awọn ọdọ ni fun imugbooro eto ọrọ-aje, idi si niyẹn ti Gomina Adeleke ṣe pinnu ṣamulo awọn ọdọ ọlọpọlọ pipe naa.
Omishore sọ siwaju pe tijọba ba le fun awọn ọdọ lanfaani lati ri ara wọn gẹgẹ bii ọkan pataki lara opo fun imugbooro ọrọ-aje, ti wọn si pese ohun gbogbo ti wọn nilo, iyatọ yoo ba ẹkajẹka lorileede Naijiria.
Lara awọn ti wọn yoo kopa ninu eto idanilẹkọọ naa ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ sayẹnsi ati imọ-ẹrọ, ileeṣẹ ọrọ aṣa ati ibudo isẹmbaye, awọn onileeṣẹ aladani atawọn ti wọn nifẹẹ si idagbasoke awọn ọdọ lawujọ wa.
O ni idanilẹkọọ ọhun yoo tun fun awọn ọdọ ti wọn ko tii mọ talẹnti wọn lanfaani lati tete mọ ọna ti wọn yoo gba wulo fun awujọ, bẹẹ ni ifimọkunmọ yoo tun wa fun awọn ti wọn ti ni oye nipa imọ ikanni ayelujara tẹlẹ.
Nipasẹ awọn akọṣẹmọṣẹ ti wọn ti ṣeto silẹ lati ba awọn ọdọ sọrọ lọjọ naa, Omishore sọ siwaju pe iyipada to nitumọ yoo ba eto ọrọ-aje kaakiri ipinlẹ Ọṣun laipẹ.
No comments:
Post a Comment