IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 4 January 2025

Ẹlẹtan ati alaimoore ni ẹgbẹ PDP - Adeṣuyi


Alaga ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party (ZLP) nipinlẹ Ọṣun, Comrade Olufemi John Adesuyi, ti sọ pe ẹgbẹ ti ko ni adehun, ti ko si moore ni ẹgbẹ oṣelu PDP. 


O ni pẹlu gbogbo aduroti ati ifọmọniyan ṣe ti ẹgbẹ ZLP fun ẹgbẹ PDP Ọṣun lasiko idibo gomina ọdun 2022 ati idibo apapọ ọdun 2023, ko si eyi ti wọn mu ṣe ninu ileri ti wọn ṣe. 


Ninu ọrọ ọdun tuntun rẹ ni Adeṣuyi ti ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati maṣe kaarẹ, ki wọn duro, ki wọn si mọ pe Ọlọrun ti ko si lẹyin alabosi yoo mu ẹgbẹ ZLP ja gbangba nipinlẹ Ọṣun. 



Adẹsuyi ṣalaye pe o ti han gbangba bayii pe ẹgbẹ ẹtan, ti ko moore ni ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọṣun pẹlu bi wọn ṣe kuna lati san gbogbo ifaraẹni jin ati atilẹyin ti wọn ri latọdọ ZLP ki wọn too de ijọba. 



O ke si awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati maṣe jẹ ki eleyii da omi irẹwẹsi si wọn lọkan, ki wọn bẹrẹ fifa oju awọn araalu mọra lati le mu ki ẹgbẹ naa gbooro, ki wọn fi rọwọ mu ninu idibo gomina to n bọ lọna lọdun 2026.


"Lọdun yii, a maa tun ṣokoto wa ṣan, a maa bẹrẹ sii ba awọn araalu sọrọ nipa oniruuru erongba rere ti ẹgbẹ ZLP ni fun wọn. Lapapọ, a maa gba ẹtọ wa l'Ọṣun, a si maa jẹ ki awọn araalu ni iriri iṣejọba to ni imọlara ẹnikeji"

No comments:

Post a Comment