IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 21 January 2025

Awọn araalu fẹsun kan Ọlọwaṣere, wọn ni gbogbo ilẹ ni kabiesi ti fẹẹ ta tan


Awọn mọlẹbi Pẹtẹlua niluu Ileṣa ti fẹsun kan ọba ilu wọn, Ọlọwaṣere ti ilu Ọwaṣere nijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakumọsa nipinlẹ Ọṣun, Ọba Oluwadare Ayọọla, pe gbogbo ilẹ to jẹ ogun-ibi awọn lo ti fẹ ta tan. 


Alaga awọn mọlẹbi naa, Agboọla Ọpẹsan, ṣalaye fawọn oniroyin laipẹ yii pe ṣe ni Ọba Ayọọla lẹdi apo pọ mọ olori ẹbi wọn, Oloye Jimoh Awẹ, ti wọn si n ta ilẹ oko mọlẹbi wọn. 

Ọpẹsan sọ siwaju pe erongba gbogbo ẹbi nigba ti wọn fi Ọba Ayọọla sori apere ni pe yoo daabo bo ogun-ibi awọn lai mọ pe ṣe ni yoo lu gbogbo rẹ ta, ti yoo si sọ awọn kan di tiẹ lai jẹ ki awọn mọlẹbi mọ. 

O ni nitori iwa ti olori ẹbi awọn hu ọhun, gbogbo mọlẹbi ti fẹnu ko lati yọ baba naa nipo olori ẹbi. 

O sọ siwaju pe awọn ti gba idajọ ile ẹjọ nibi ti adajọ ti paṣẹ fun Ọba Ayọọla lati maa san owo to ba gba lori ilẹ naa fun awọn mọlẹbi ti wọn ni i, sibẹ, ọba yii ko dahun. 

Ọpẹsan tẹ siwaju pe Oloye Jimoh Awẹ ati Ọba Oluwadare Ayọọla ti gbimọ pọ, wọn si ti sọ ara wọn di ajagungbalẹ, alayọjuran ati ọta mọlẹbi Pẹtẹlua. 

Bakan naa ni wọn ni ẹnikẹni to ba ti sọrọ lori iwa ọba yii lawọn ọlọpaa n ko da si atimọle, eleyii ti wọn ni o le da wahala nla silẹ lagbegbe naa tijọba ko ba tete da si i. 

Wọn waa ke si ijọba ipinlẹ Ọṣun ati Ọwa Obokun ilẹ Ijeṣa, Ọba Clement Hasstrup Adeṣuyi, lati tete da si ọrọ yii ko to di eyi ti yoo di wahala nla. 

Gbogbo mọlẹbi naa ke sijọba lati yọ Ọba Ayọọla ni ipo gẹgẹ bii Ọwaṣere ki alaafia le jọba niluu naa, bẹẹ ni wọn ni Oloye Awẹ ko gbọdọ pe ara rẹ ni olori ẹbi naa mọ. 

Nigba to n sọrọ lori ẹsun naa, Oloye Awẹ sọ pe irọ ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun ati pe awọn ti wọn fẹẹ ba oun lorukọ jẹ ni wọn wa nidi ẹ. 

Gbogbo igbiyanju wa lati ba Ọwaṣere sọrọ ni ko so eso rere nitori foonu rẹ ko lọ

No comments:

Post a Comment