IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 26 January 2025

Arẹgbẹṣọla atawọn ọmọlẹyin rẹ ti kuro ninu ẹgbẹ APC, wọn kede igbesẹ tuntun ti wọn fẹẹ gbe


Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ Omoluabi Progressives ti i ṣe igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun ti fẹnuko lati fi ẹgbẹ onigbalẹ silẹ bayii.


Nibi ipade awọn lookọlookọ ninu ẹgbẹ naa, eleyii to waye niluu Ileṣa lonii ọjọ Aiku, ni wọn ti sọ pe awọn ṣetan lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu miran to ba nitumọ ṣaaju idibo gomina to n bọ lọdun 2026.

Lara awọn idi ti wọn sọ pe o mu awọn kuro ninu APC Ọṣun ni idẹyẹsi, lile ni kuro ninu ẹgbẹ, pipaṣẹ pe ka lọọ rọọkun nile lai gbọ tẹnu ẹni, aikanisi atawọn iwa miran to wa lọwọ awọn adari ẹgbẹ naa.

Nigba to n ba awọn Omoluabi Ptogressives sọrọ, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla to jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun gboṣuba fun ifaraẹnijin ati idurosinsin ti wọn ni fun ijọba to duroore.

O ni asiko ti to bayii lati ṣiṣẹ fun aṣeyọri ati afojusun Omoluabi Progressives lati sagbekalẹ ijọba to dara l'Ọṣun. O ni awọn ṣetan lati darapọ mọ ẹgbẹ to ba ni erongba rere fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.

Ṣaaju ninu ọrọ alaga Omoluabi Progressives, Alhaji Azeez Adeṣiji, o dupẹ fun bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣe fi ohun ṣọkan lati gbe igbesẹ akin naa.

O rọ wọn lati maṣe kaarẹ, ki wọn maa ba ipade lọ ni gbogbo wọọdu wọn, pẹlu idaniloju pe ijọba to duroore yoo fẹsẹ mulẹ l'Ọṣun lọdun 2026.

No comments:

Post a Comment