Gbajugbaja onimọ ẹsin Islam niluu Ẹdẹ, Imaamu Abdullahi Oyewale Lawal, ti tan imọlẹ si ohun ti ẹsin ati aṣa sọ nipa awuyewuye to gba ori ẹrọ ayelujara kan lorii bi Timi ti ilu Ẹdẹ, Ọba Munirudeen Adeṣọla Lawal, ṣe kunlẹ lẹgbẹẹ Emir ilu Ilọrin, Sulu Gambari, nigba ti wọn n sọrọ ninu aafin Emir laipẹ yii.
Gẹgẹ bi baba naa ṣe wi, ko si nnkan to buru ninuu bi Ọba Adeṣọla Lawal ṣe bu ọla fun Emir ọhun.
Imaamu Oyewale ni, 'Orukọ mi ni Imaamu Abdullahi Oyewale Lawal, Imaamu Agba Ọlọrunlomẹruẹ Central Mosque niluu Ẹdẹ, ti mo tun jẹ igbakeji aarẹ fun igbimọ awọn oniwaasi ẹsin Islam (Council of Islamic Preachers) ni Guusu Iwọ-Oorun orileede yii.
"Baba Timi o ṣe aṣiṣẹ rara nitori Islam sọ pe ka pọn agbalagba le. Agbalagba ni Emir Ilọrin, ki i ṣe ọmọ kekere, ni ti dide ori aga ọla, o ṣaaju Baba Timi Ẹdẹ, ni ti ọjọ-ori, o ju baba wa Timi Ẹdẹ lọ.
"Ohun tawọn eeyan n wo ni pe ọba jọ lawọn mejeeji, ti ẹ ba ni ọba lawọn mejeeji, ṣe ọjọ-ori kan naa lo wa lori wọn? Ṣe igba kan naa ni wọn ja ewe oye le wọn lori?
"Tawọn eeyan ba tun wa n ro pe ọba alade n kunlẹ fun ọba onilawani, ninu lawani ati ade, eewo lagba? Emi wa nibi ti ọrọ yẹn ti ṣẹlẹ, ki i ṣe pe baba diidi kunlẹ, nigba ti wọn debẹ, wọn lọọ ki Emir, wọn bọ Emir lọwọ, Emir waa fẹ ba wọn sọrọ, baba yẹn dẹ ti dagba, wọn o le gbọ ọrọ rẹ lọọkan, wọn ni lati sunmọ ọn, ki wọn gbe eti si wọn lẹnu.
"Baba alubarika ni Emir ilu Ilọrin, Ilọrin ki i ṣe ilu kekere, ilu ẹsin ni, gbogbo nnkan teeyan ba n gbe bọ latibikibi to ti n bọ, to ba de Ilọrin, yoo da a silẹ, ilu imọ ni, ilu alukuraani ni, a o si gbọdọ foju kere wọn bo tilẹ wu ko mọ.
"Yatọ si eleyii, wọn tun gbọdọ ro o pe Islam fi aaye ka bọwọ fun aṣiwaju silẹ. Ẹni to ba ṣapọnle agbalagba, Ọlọrun yoo pọn oun naa le, ẹni to ba si foju kere agbalagba, Ọlọrun a foju yẹpẹrẹ tiẹ naa. Nitori naa, ko si aṣiṣe kankan ninu nnkan ti Baba Timi ṣe.
"Ti a ba si tun n sọ nipa ti aṣa, ẹsin ti gbe aṣa mi, tori ti ẹsin ko ba gbe aṣa mi, ile kọọkan o nii ni mọṣalaaṣi loni. Aṣa ni ka bọ eegun, ka bọ ogun, nilee tiwa to jẹ ile ọlọdẹ, ogun la maa n bọ nibẹ, ṣugbọn ẹ ko le ri ogun nibẹ mọ bayii.
"Aṣa naa bu ọla fun ẹsin, o fun ẹsin lapọnle, o si fun agbalagba lapọnle. Ninu aṣa Yoruba, ti agbalagba ba dide lori apoti kan, ọmọde to ba fẹẹ joko nibẹ gbọdọ gba iyọnda lọdọ agbalagba yẹn. Ti agba o ba tii mẹran lasiko ounjẹ, ọmọ kekere kankan o le mu ẹran, ara aṣa naa ni".
No comments:
Post a Comment