IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 15 January 2025

Adari rere, to ṣe e ṣe awokọṣe ninu oṣelu ni Oloye Bisi Akande - Igbimọ Agba Ọṣun


Igbimọ Agba Ọṣun ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ti yin gomina tẹlẹ, Oloye Bisi Akande, lawo, fun ipa ribiribi to ti ko ninu eto oṣelu nipinlẹ Ọṣun. 


Ninu ọrọ ikini ku oriire ayajọ ọdun kẹrindinlaadọrun ti Baba Akande de ile aye ni alaga igbimọ naa, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ti sọ pe ko si oloṣelu to gba abẹ itọni baba naa kọja ti ko ṣaṣeyọri ninu oṣelu. 


Gẹgẹ bi Akinwumi ṣe wi, ipa manigbagbe ni ọlọjọọbi ti ko lori aye ọpọlopọ eniyan ninu oṣelu, ibagbepọ ẹda, aanu ṣiṣe, aṣa ati ifọmọniyan ṣe. 


Igbimọ naa dupe fun atilẹyin ti Oloye Bisi Akande n ṣe loorekoore fun wọn nigbakuugba ti wọn ba n ṣe ojuṣe wọn lati ri i pe ohun gbogbo n lọ deede ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun. 


Bi Oloye Akande yoo ṣe naa ṣe ayajọ naa lọjọ kẹrindinlogun oṣu kin-in-ni ọdun yii, wọn gbadura pe ki Allah tubọ maa daabo bo baba naa, ko si maa darii rẹ ninu alaafia pipe.

No comments:

Post a Comment