IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 26 January 2025

2026: Adeleke kọ lẹta sawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC l'Ọṣun, o ni o to gẹẹ


Gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ọṣun, o n gbe mi lọkan lati sọrọ lori awọn nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ wa lọwọlọwọ, paapaa, lori ọrọ ẹni ti yoo jẹ oludije funpo gomina.


O pọn dandan lati mọ pe gbogbo eeyan pata lo ni ẹtọ labẹ ofin lati du ipokipo to ba wu u niwọn igba to ba ti jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu.

Ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, a ni awọn adari ti wọn tọ si iyi ati ọla latọdọ wa. Baba Bisi Akande jẹ babaa-baba ati adari patapata, nigba ti Ọlọlajulọ, Alhaji Adegboyega Isiaq Oyetọla jẹ baba ati adari. Senator Dr. Ajibọla Surajudeen Baṣiru, to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ ati Alhaji Tajudeen Lawal (Sooko) gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ nipinlẹ Ọṣun naa jẹ adari.

A gbọdọ mọriri akitiyan Baba Akande ati Alhaji Oyetọla lati ri i pe ipo nlanla bọ si wa lọwọ l'Ọṣun. Manigbagbe ni ipa ti wọn ko lati jẹ ki Dokita Baṣiru Ajibọla di akọwe apapọ ẹgbẹ wa.

O wa ninu akọsilẹ pe Alhaji Gboyega Oyetọla ti ṣe gudugudu meje, yaaya mẹfa fun ẹgbẹ oṣelu wa l'Ọṣun, gẹgẹ bii minisita, o ti na owo lati ri i pe ẹgbẹ yii wa papọ lẹyin ti a bọrẹlẹ ninu idibo ọdun 2022, ti a si kuro nijọba.

Bakan naa lo tun wa lakọsilẹ pe, latigba ti wọn ti da ipinlẹ Ọṣun silẹ, Oyetọla ni minisita kan ṣoṣo to ṣokunfa iyansipo oniruuru latọdọ ijọba apapọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ.

 1. Dokita Ajibọla Baṣiru di akọwe apapọ fun ẹgbẹ APC nipasẹ akitiyan Alhaji Oyetọla atawọn mi-in.
 2. Aṣiwaju Bọla Oyebamiji di alakoso ajọ NIWA nipasẹ akitiyan Oyetọla.
 3. Ẹnjinia Ọlalekan Badmus di ọga agba ajọ NPA nipasẹ Alhaji Oyetọla
 4. Ẹnjinia Olurẹmi Ọmọwaiye di alakoso  Federal Housing Authority nipasẹ adari wa, Oyetọla
 5. Dokita Festus Olowogboyega naa di kọmiṣanna fun ajọ awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ nipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun nipasẹ igbiyanju Oyetọla.
 6. Ọjọgbọn Ṣiyan Oyewẹsọ di alaga igbimọ alaṣẹ Ọbafẹmi Awolowọ University nipasẹ akitiyan Alhaji Oyetọla nikan ṣoṣo.
 7. Dokita Amidu Tadeṣhe di kọmiṣanna fun ajọ eleto ikaniyan, National Population Commission.
 8. Ẹnjinia Fatai Adeyẹmi di alakoso NIMASA nipasẹ igbiyanju Oyetọla ati ọpọlọpọ ipo ijọba apapọ miran.
Nitori naa, ọmọ ẹgbẹ ti ki i ba ṣe alaimoore gbọdọ bọwọ fun iru adari bayii.

Ṣe lo yẹ ka gboriyin fun Oyetọla fun ipa ribiribi to n ko lati so ẹgbẹ papọ lati ọdun 2022, ki i ṣe ki ẹnikẹni tun maa bu ẹnu atẹ lu u nitori erongba kankan.

O ti fi awọn amuyẹ adari tootọ han pẹlu bo ṣe di ẹgbẹ mu, to si n mu nnkan meremere wa sipinlẹ Ọṣun nipasẹ oniruuru ipo latọdọ ijọba apapọ. Ko si ẹni to ṣeruu rẹ ri; yala latẹyinwa tabi lọwọlọwọ bayii. Oyetola ki i ṣe ẹni arifin! O tọ si ọla ati ọwọ latọdọ gbogbo eeyan lai fi ti ipo ti a le wa ṣe. 

Latari idi eyi, mo rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati ba ara wọn sọrọ, ki wọn si mọ pe ọmọ iya kannaa ni wa labẹ ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo. Ọrọ ipo gomina ko gbọdọ sọ wa di ọta ara wa.

Gbogbo agbegbe ati ilu ni wọn ni ẹtọ lati beere fun tikẹẹti yii, a ko si gbọdọ ri ara wa bii ọta. Gbogbo wa fẹẹ pọn omi latinu kanga kannaa ni, a fẹẹ ra ọja latinu ṣọọbu kannaa, ẹnikẹni ko waa gbọdọ maa sọrọ kobakungbe si ẹnikeji nitori pe o n lọọgun fun ilu ati agbegbe rẹ.

Ọmọ ilu Oṣogbo ni ẹtọ lati lepa afojusun Oṣogbo, bẹẹ ni ọmọbibi ilu Ifẹ ni ẹtọ si i. Ọmọbibi ilu Gbọngan ni ẹtọ labẹ ofin lati beere fun tikẹẹti yii, nigba ti ọmọ ilu Ileṣa le beere, bakan naa ni awọn Iwọ-Oorun Lo Kan ni ẹtọ lati lepa tikẹẹti yii.

Gbogbo eeyan kaakiri agbaye ni wọn fẹ ohun to dara julọ fun agbegbe wọn, nitori naa, ko si nnkan to buru ti eeyan ba beere fun ẹtọ rẹ. Ṣugbọn a gbọdọ kiyesara lati mọ pe a ko gbọdọ lo ilepa wa lati da iyapa silẹ ninu ẹgbẹ. Ẹgbẹ lo ga ju lọ.

Niwọn igba ti gbogbo wa ti fi ẹnu ko pe Baba Adebisi Akande ati Alhaji Gboyega Oyetọla ni aṣaaju ẹgbẹ wa l'Ọṣun, ti a si nigbagbọ ninu idari wọn, ẹ jẹ ka fi suuru duro de aṣẹ ti wọn yoo pa lori ibi ti a maa lọ. Ẹ jẹ ka parapọ soju kan. Fun emi o, ọrọ iṣọkan ẹgbẹ wa ko ṣe e dunadura rara.

Gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ, ti a si gbagbọ, ẹtọ Oyetọla ni lati kọkọ sọ pe oun ko du ipo gomina mọ, abi ẹnikẹni wa to n gbero lati lọ si idibo abẹle pẹlu rẹ? 

Ti ko ba si, gbolohun wi pe 'Ti Oyetọla ko ba dupo mọ' yẹ ko maa ṣaaju fifi erongba ẹnikẹni han lori ipo to ga yii. 

Ju gbogbo rẹ lọ, Ọlọrun lo ni agbara, O si maa n fi i fun ẹnikẹni to ba wu U lasiko ati igba kọọkan. Ẹ maṣe jẹ ka mu ara wa lọta, ṣugbọn ka ṣiṣẹ papọ fun aṣeyọri ẹgbẹ wa.

Ọta kan ṣoṣo ti a ni ni ẹgbẹ oṣelu PDP, ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ APC araa wa. Pipe ara wa loriiṣiriṣi orukọ ati sisọ ọrọ alufansa si ara wa ti to gẹẹ! 

Prince Adebayọ Adeleke (BANIK)

No comments:

Post a Comment