Igbimọ apapọ awọn ọmọ Yoruba lagbaye, Yoruba Council Worldwide (YCW), ti gboṣuba fun ijọba apapọ orileede Naijiria labẹ Aarẹ Bọla Tinubu fun bo ṣe paṣẹ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ko gbọdọ gbe papakọ ofurufu to wa niluu Ido-Ọṣun lọ si ilu Ẹdẹ.
Gẹgẹ bi aarẹ igbimọ naa, Aarẹ Ọladọtun Hassan ati akọwe rẹ, Bashọrun Isaac Ajibọla, ṣe wi, igbesẹ ti aarẹ gbe naa fi han pe ijọba Tinubu ko fọwọ si iwa iyanjẹ ati iwa fa-mi-lete-n-tutọ tijọba ipinlẹ Ọṣun fẹẹ hu.
Ṣaaju ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti kede pe ijọba oun yoo gbe papakọ ofurufu to ti wa niluu Ido-Ọṣun nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ lati ọdun 1936 naa kuro lọ si ibudo tuntun niluu Ẹdẹ eleyii ti wọn yoo ṣe ifilọlẹ rẹ lọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila yii.
Ṣugbọn latigba tikede naa ti jade ni oniruuru ifẹhonu han ti bẹrẹ, ti awọn lamẹẹtọ ilu si n kọwe sileeṣẹ aarẹ pe iwa ifọwọọla-gbani-loju ni ilu Ẹdẹ fẹẹ hu.
Wọn ke si minisita fun ọrọ irinna oju ofurufu, Festus Keyamo ati ojugbaa rẹ nileeṣẹ-ode lati maṣe wa sibi ifilọlẹ ibudo tuntun naa, ti wọn si sọ pe igbesẹ Adeleke ọhun le da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru.
Bakan naa ni ẹgbẹ YCW kọ lẹta si Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lori ọrọ naa. Wọn ṣapejuwe gbigbe papakọ ofurufu naa kuro ni Ido-Ọṣun lọ si Ẹdẹ gẹgẹ bii iwa aitọ, ti ko si ba ofin pinpin nnkam dọgbandọgba mu.
Wọn ni latilẹ ni ede aiyede ti wa laarin ilu Ido-Ọṣun ati ilu Ẹdẹ, bi Gomina Adeleke si ṣe fẹẹ gbe papakọ naa kuro niluu Ido-Ọṣun, ti wọn si fẹẹ yi orukọ rẹ pada si Isiaka Adeleke International Airport, Ede yoo tubọ da wahala nla silẹ ni.
Wọn ke si awọn aṣaaju ilẹ Yoruba, awọn ori-ade, awọn ajafẹtọ-ọmọniyan, atawọn lamẹẹtọ kaakiri orileede Naijiria lati ṣugba ilu Ido-Ọṣun lori ọrọ naa. Wọn ni ṣe ni ilu Ẹdẹ fẹẹ lo agbara le Ido-Ọṣun lori.
Ẹgbẹ naa gboju aagan si bo ṣe jẹ pe ilu abinibi gomina, Ẹdẹ, nikan ni wọn n gbe oniruuru iṣẹ akanṣe lọ, eyi ti wọn lo ṣafihan gomina gẹgẹ bii onimọtara-ẹni nikan, bẹẹ ni wọn bu ẹnu atẹ lu awọn oludamọran ti wọn yi Adeleke ka, pe wọn ko gba a nimọran rere.
Amọ ṣa, ileeṣẹ to n ri si ọrọ irinna ofurufu lorileede yii ti kọ lẹta sijọba ipinlẹ Ọṣun pe ki wọn dawọ duro lori ọrọ papakọ ofurufu naa titi digba ti iwadii yoo pari lori idi ti wọn ṣe fẹẹ gbe e, ayẹwo lori owo ti awọn ijọba to lọ ti na lori rẹ ati anfaani ti ibudo tuntun ti wọn fẹẹ gbe e lọ ni lori ibi ti wọn ti fẹẹ gbe e kuro.
No comments:
Post a Comment