IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 3 December 2024

Ọṣun: Ta lo yinbọn pa Ọgbẹni Sikiru sinu oko rẹ niluu Ilobu?


Bi a ṣe n kọ iroyin yii lọwọ, ara o rokun, ara o rọ adiyẹ niluu Ilobu nijọba ibilẹ Irẹpọdun ati ilu Ifọn-Orolu nijọba ibilẹ Orolu nipinlẹ Ọṣun, lori iku ọkunrin kan ti wọn pa sinu oko rẹ lọsan oni. 


Ọsan oni Tusidee ni wọn fi mọto Jiịpu alawọ dudu kan gbe oku Ọgbẹni Ọnaọlapọ Sikiru lọ si aafin Olobuu ti Ilobu. Wọn ni inu oko rẹ to wa ṇi Oke-Ekutu ni Ilobu ni wọn pa baba to jẹ ọmọ agboole ọba niluu ọhun si. 


Ṣugbọn ṣe ni awọn eeyan ilu Ilobu n tẹnumọ ọn pe awọn janduuku kan lati ilu Ifon-Orolu ni wọn huwa buburu naa ati pe orukọ olori wọn ni Ọgbẹni Sikiru n pariwo pe o yinbọn mọ oun titi to fi dagbere faye. 


Wọn ke si Gomina Ademọla Adeleke lati tete wa nnkan ṣe si iṣẹlẹ iṣekupani ọhun ko too di pe yoo di eyi ti apa ko nii le ka mọ. 


Amọ ṣa, agbarijọpọ awọn ọmọ ilu Ifọn-Orolu ti sọ pe irọ to jinna sootọ ni ẹsun ti awọn eeyan ilu Ilobu fi kan wọn. 


Ninu atẹjade kan ti Ọmọọba Jide Adelaja Akinyọoye fi sita, ni wọn ti ke si awọn oṣiṣẹ alaabo pe ki wọn tete ṣewadi iṣelẹ naa, ki wọn si fojuu alabosi han faraye ri. 


Amọ ṣa, awọn ọlọpaa ilu Ilobu ti gbe oku naa lọ sile igbokupamọ si ti ileewosan ẹkọṣẹ UNIOSUN.

No comments:

Post a Comment