IROYIN YAJOYAJO

Friday, 20 December 2024

Ọrọ ipo Alara wa ni kootu, a ko mọ si gbigbe ade fun ẹnikẹni lọjọ ayẹyẹ Ara Day o - Awọn ọlọmọọba ṣekilọ


Awọn idile ọlọmọọba niluu Ara nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe awọn ko mọ si ahesọ to n lọ kaakiri bayii pe wọn yoo gbe ade le ẹnikan lori gẹgẹ bii Alara lọjọ ayẹyẹ Ara Day to n bọ lọna. 


Wọn ni ayẹyẹ Ara Day ti wa ko too di pe wọn da ipinlẹ Ọṣun silẹ, o si jẹ ọkan lara agbekalẹ agbarijọpọ awọn ọmọ ilu naa, ṣugbọn awọn ko nii faramọ ọn ki ẹnikẹni lo anfaani ayẹyẹ naa lati huwa ti ko tọ. 


Nibi ipade apapọ ti awọn idile ọlọmọọba naa ṣe niluu Ara laipẹ yii, olori mọlẹbi ti wọn n pe ni Ọmọ Mọjọ, eleyii tijọba mọ si, Ọmọọba Emmanuel Ọladẹjọ Ilufoye, sọ pe ọrọ ipo Alara wa ni kootu. 


O ni kootu nikan lo le sọ ẹni to jẹ Alara ti ilu Ara gan-an, nitori naa, ko si idile ọlọmọọba kankan to mọ si erongba awọn kan lati gbe ade le ẹnikẹni lori gẹgẹ bii Alara lọjọ ayẹyẹ Ara Day. 


Bakan naa ni akọwe awọn ọlọmọọba ọhun, Ọmọọba Akinọla David sọ pe ko si Alara kankan lọwọlọwọ bayii, ati pe ti Dokita Iwindapọ, ẹni ti ẹjọ rẹ ṣi wa ni kootu, ba fẹẹ ṣe ayẹyẹ igbade funraarẹ, ṣe ni ko mu ọjọ kan, ko gbọdọ da a pọ mọ ọjọ Ara Day. 


Lorukọ gbogbo awọn ọlọmọọba, wọn waa ki gbogb̀o awọn ọmọ ilu Ara lọkunrin ati lobinrin ku imura ayẹyẹ Ara Day ati ti ọdun tuntun.

No comments:

Post a Comment