IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 10 December 2024

Ọpẹ o! Gomina Adeleke tẹwọ gba àtẹ ikẹkọọ lori ẹrọ ayelujara fun awọn akẹkọọ


Lati le mu ki ikẹkọọ rọrun fun awọn akẹkọọ kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ijọba Gomina Ademọla Adeleke ti darapọ mọ awọn ipinlẹ ti wọn ti ṣiṣọ lorii atẹ ikẹkọọ lori ẹrọ ayelujara (Nigerian Learning Passport) bayii. 


Eleyii lo mu ko di ipinlẹ mọkanlelogun kaakiri orileede Naijiria to gbaruku ti eto ikẹkọọ to fun awọn akẹkọọ atawọn ti ko lanfaani lati lọ sileewe ọhun lanfaani si ẹkọ lai si idiwọ kankan. 


Eto naa, eleyii ti ijọba ipinlẹ Ọṣun pẹlu ibaṣepọ ajọ Teen Awareness Initiative (TTAI) kede rẹ ninuu gbọngan Ọlagunsoye to wa ninuu Fasiti Oṣun, ni ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọde, United Nations International Children's Emergency Fund ( UNICEF), yoo maa ṣamojuto rẹ.


Ninu apilẹkọ rẹ, Gomina Ademọla Adeleke sọ pe ọna abayọ miran, to si rọrun, si eto ikẹkọọ to ye kooro lori ẹrọ ayelujara ni eto naa. 


Adeleke, ẹni ti olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Ayanlẹyẹ Aina, ṣoju fun, ṣalaye pe bi atẹ ikẹkọọ naa ṣe wulo fun awọn akẹkọọ, lo wulo fun awọn olukọ, bẹẹ lo si tun wulo fun awọn olukọọ kaakiri agbaye. 


O ni nipasẹ rẹ, iyatọ yoo ba esi idanwo ti awọn akẹkọọ ba n ṣe, yoo si fun wọn lanfaani ikẹkọọ siwaju sii lai si laalaa nitori wọn yoo ti ni igboya lati kojuu idanwo nibikibi. 


Adeleke gboṣuba fun ajọ UNICEF ati TTAI fun eto naa, o ni yoo sọ awọn akẹkọọ di ẹni to le danuu ro daadaa, ti wọn yoo si le pese ọna abayọ si ipenija ti wọn ba doju kọ ninu ẹkọ wọn. 


Ninu ọrọ tirẹ, kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Dipọ Eluwọle dupẹ lọwọ Gomina Adeleke fun oniruuru eto to n gbe lati tun igba eto ẹkọ sọ bii ẹni sọgba latigba to ti de ori aleefa. 


O ni eto tuntun yii jẹ okoowo to dara julọ ti ijọba to ba nifẹẹ idagbasoke ipinlẹ rẹ nipasẹ eto ẹkọ le ṣe lati le rii pe awọn ọdọ rẹ di amuyangan kaakiri agbaye. 


Bakan naa ni akọṣẹmọṣẹ ninu ajọ UNICEF, Babagana Aminu, sọ pe gbogbo ilana ẹkọ nileewe patapata lo wa ninu atẹ ikẹkọọ naa, ko si si bi akẹkọọ ṣe le fọkan si i ti ko nii ṣaṣeyọri ninu ẹkọ rẹ.

No comments:

Post a Comment