Araba awo ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuubọn, ti kilọ fun awọn ti wọn n fi oju buruku wo ẹsin ibilẹ lati dẹkun iru iwa bẹẹ.
O ni ọpọ gbagbọ pe ero ina ni ẹnikẹni to ba n ṣe ẹsin ibilẹ, eleyii to si jinna si ootọ patapata nitori iwa ọwọ ẹnikọọkan ni yoo sọ ibi ti yoo sọ ẹru rẹ ka, ko si sẹni to mọ ẹni ti yoo wọna.
Nibi ayẹyẹ Ọláọjọ Royal Day alakọọkọ iru ẹ to waye ninu aafin Olufọn ti ilu Ifọn, Ọba Peter Oluwọle Ipadeọla Akínyọọ́yè Kẹta, ni Baba Ẹlẹbuubọn ti sọ pe ẹsin ilẹ okeere ti gba aaye ẹsin abalaye mọ awọn ọmọ orileede yii lọwọ.
Oloye Ifayẹmi, ẹni to jẹ oludanilẹkọ pataki nibi ayẹyẹ naa sọ pe ti eeyan ba kuro lorileede Naijiria, to lọ si awọn orileede bii Brazil, yoo ri i bi awọn alawọ funfun ṣe n ṣapọnle ẹsin ati aṣa to ti di yẹpẹrẹ nilẹ wa.
O ke si awọn ọmọbibi ilu Ifọn lati mojuto oriṣa Ọbatala ti gbogbo aye mọ wọn mọ, ki wọn ma si jẹ ki aṣa naa parun nipasẹ aibikita wọn.
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọṣun, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, ṣalaye pe ilu Ifọn atawọn ilu mejeeji to yi i ka, iyẹn Ilobu ati Ẹrin Ọṣun jẹ awọn ilu tijọba mu ọrọ wọn lọkunkundun.
Alimi ṣalaye pe igbimọ tijọba gbe kalẹ lati wa ojutu si ọrọ alaafia agbegbe naa ti ṣiṣẹ takuntakun, nigba to ba si fi maa di ibẹrẹ ọdun tuntun, abọ iṣẹ wọn yoo jade, ti ireti si wa pe yoo pese alaafia patapata sagbegbe naa.
O ke si awọn ọmọ ilu mẹtẹẹta lati gba alaafi laaye nitori ko le si itẹsiwaju kankan lagbegbe ti gbodo-n-roṣọ ba ti n waye.
Ninu ọrọ tirẹ, ọkan lara awọn agbẹnusọ ilu naa, Ọmọọba Jide Akinyọọye, sọ pe ileri lati ọdọ ijọba lori wahala naa ti n di lemọlemọ lai si imuṣẹ rẹ.
O rọ ijọba lati tete wa ojutuu patapata si ọrọ wahala naa, nitori gẹgẹ bo ṣe wi, ọrọ naa ti n lọ si ipele ti awọn agbaagba ilu ko nii le ka awọn ọdọ lapa ko.
No comments:
Post a Comment