IROYIN YAJOYAJO

Monday, 2 December 2024

Ikunlẹ abiamọ o! Oṣiṣẹ aṣọbode, iyawo atawọn ọmọ mẹrin jona mọle l'Ọṣun


Gbinringbinrin ni agbegbe Akankan niluu Ẹdẹ nipinlẹ Ọṣun kan bayii lori iṣẹlẹ ijamba ina kan to ṣẹlẹ nibẹ nidaji oni Mọnde, ọjọ keji oṣu kejila. 

Nnkan bii aago mẹta idaji la gbọ pe ina dede ṣẹyọ ninu ile ọkunrin aṣọbode naa, Tijani Kabiru, ki awọn oṣiṣẹ panapana si too debẹ, ọkunrin naa, iyawo rẹ ati ọmọ mẹrin ti jona guruguru. 


Gbagede gbọ pe akọbi ọkunrin ọhun nikan lo raaye sa asala fun ẹmi rẹ, nigba ti awọn obi rẹ pẹlu awọn aburo rẹ mẹrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹwaa si mẹta ba iṣẹlẹ abami naa lọ. 


Gbogbo awọn olugbe agbegbe naa, iyẹn, Custom Tijani Kabiru Street, Akankan Area, Ẹdẹ, ni ko mọ ohun to ṣokunfa ijamba ina naa titi di asiko ti a n ko iroyin yii. 


Ṣugbọn alakoso ileeṣẹ ajọ panapana l'Ọṣun, Ọlaniyi Alimi, sọ pe aago mẹta aarọ kọja ogun iṣẹju lawọn gba ipe nipa iṣẹlẹ naa, kia lawọn si kọja sibẹ. 


O ni yatọ si eeyan mẹfa to jona mọnu ile naa, dukia ti owo rẹ to igba miliọnu naira lo ba iṣẹlẹ naa lọ. 


Gbagede gbọ pe wọn ti sinku awọn eeyan naa nilana ẹsin musulumi.

No comments:

Post a Comment