IROYIN YAJOYAJO

Friday, 6 December 2024

Gomina Makinde, ṣọra lọdọ Adeleke o, ẹyin ẹlẹyin ladiyẹ rẹ n ṣaba le lori o - APC Ọṣun kilọ


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ọṣun ti kilọ fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde, lati ṣọra, ko si ṣewadi ohunkohun ti ojugba rẹ l'Ọṣun ba pe e lati ba oun dawọọ idunnu le lori lọjọ iwaju. 


Laipẹ yii ni Makinde lọ sipinlẹ Ọṣun nibi to ti ba Gomina Ademọla Adeleke ṣi oju-ọna alabala meji to lọ lati Testing Ground si Ileṣa Garage niluu Oṣogbo. 


Ṣugbọn ẹgbẹ APC ṣalaye pe bii igba teeyan n kun atike soju ọmọ ọlọmọ ni ọrọ naa nitori ida ọgọrin ninu ida ọgọrun ọna ti Adeleke sọ pe oun ṣi ọhun nijọba Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla pẹluu ti Alhaji Oyetọla ti ṣe ki wọn too lọ. 


Ninu atẹjade ti alukoro ẹgbẹ naa, Oloye Kọla Ọlabisi fi sita, ni APC ti ni iyalẹnu lo jẹ bi Makinde, ẹni to jẹ ẹnjinia ko ṣe mọ pe iṣẹ ajanbaku loun waa ṣiṣọ loju ẹ lasiko to rin oju-ọna ọhun kọja. 


Atẹjade ọhun ni, "Biliọnu mẹẹdogun naira nijọba Arẹgbẹṣọla ati Oyetọla ti na lori ọna ọhun, to si jẹ pe kilomita to le ni marun-un ni Oyetọla nikan ṣe nibẹ, biliọnu mẹta naira pere ni owo iṣẹ naa ku lati pari nigba naa, bawo waa ni ẹni to ṣe ida ogun ninu ida ọgọrun iṣẹ ṣe n pariwo ẹnu kaakiri bii ẹni pe oun lo ṣe eyi to pọ ju ninụ ẹ. 


"A ko si le ba Adeleke wi pupọ, asiko tijọba Oyetọla n ṣe oju ọna Stadium si Old Garage ọhun lo n sa kolobakoloba kaakiri orileede Amẹrika, ko mọ nnkan kan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ọṣun. 


"A ke si Makinde lati maa ṣewadii iṣẹkiṣẹ ti Adeleke ba pe e si lọjọ iwaju ko too wa nitori ẹyin ẹlẹyin lo ku ti adiyẹ ijọba rẹ n ba le kaakiri nipinlẹ Ọṣun bayii. 


"A tun ba Makinde kẹdun pẹluu ileri to ṣe fun Adeleke pe oun yoo ran an lọwọ lati pada sile ijọba Ọṣun lọdun un 2026 nitori Adeleke funraa rẹ mọ ibi ti ina ti n jo oun labẹ aṣọ, o si mọ pe ala ti ko le ṣẹ ni ijawe olubori oun ninu idibo gomina to n bọ"

No comments:

Post a Comment