Awọn ọmọ ile ọlọmọọba Awánibákú, Ọlaitan ati Òrúnmọ̀ niluu Iran nijọba ibilẹ agbegbe Guusu Ayedire nipinlẹ Ọṣun ti ke gbajare si Gomina Ademọla Adeleke pe awọn kan ti fẹẹ tẹyin gbe ru awọn lori ọrọ ipo ọba ilu naa.
Awọn idile mẹtẹẹta to n jẹ ọba ilu Iran ṣalaye pe ajeji godogbo ni ọkunrin kan, Kunle Ọmọlọla ti awọn kan mu orukọ rẹ lọ fun gomina pe yoo jẹ Onírán, bẹẹ ni ko sẹni to da a mọ ninu ile Ọlọmọọba Ọlaitan to ti sọ pe oun ti wa.
Ninu lẹta kan ti agbẹjọro fun awọn eeyan naa, Ọgbẹni Ahmad Abdullateef kọ lati ọfiisi Apex Solicitor, si Gomina Adeleke lọjọ keji oṣu kejila ọdun yii, ni wọn ti sọ pe adabọwọ ni awọn oṣiṣẹ kansu agbegbe Guusu Ayedire ṣe lori ọrọ iyansipo naa.
O ni ko si eyi ti wọn ranṣẹ si laarin idile mẹtẹẹta to n jẹ Oluran niluu Iran, saa deede lawọn si gbọ pe wọn ti mu orukọ Ọmọlọla lọ sọdọ gomina l'Oṣogbo.
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu lẹta naa, "A n rawọ ẹbẹ si gomina wa lati maṣe faaye gba iyansipo Ọnarebu Kunle Ọmọlọla gẹgẹ bii Oluran ti ilu Iran, idi ni pe ọmọbibi abule Ẹlẹfọn ni Oke-Ọṣun ni, ko ni ẹtọ kankan si oye yẹn rara.
"Lẹyin ti Oniran tẹlẹ, Ọba Sawiyu Alao Adewọlu Kinni, waja lọjọ karun-un oṣu karun-un ọdun 2023, awa idile ọlọmọọba n reti kijọba bẹrẹ eto lati yan Oniran tuntun.
"Ṣugbọn a kan deede gbọ pe wọn ti mu ẹnikan to n jẹ Ọnarebu Kunle Ọmọlọla gẹgẹ bii Oniran ti ilu Iran tuntun.
"A ran awọn aṣoju lọ sọdọ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ agbegbe ni Guusu Ayedire lati wadii ohun ti a gbọ, nibẹ ni awọn ti wọn wa lọfiisi oye jijẹ ti sọ fun wa pe eeyan meji pere lo gba fọọmu lati fifẹ han si ipo Oniran.
“Nigba ti a pe wọn nija pe nigba wo ni wọn gbe ikede jade pe kawọn ọmọ-oye waa gba fọọmu, wọn ni ṣe lawọn lẹ iwe ikede naa mọ ara ogiri sẹkiteriati kansu naa.
“Gomina, yatọ si pe wọn ko fi eto kankan to awa idile ọlọmọọba leti, Kunle Ọmọlọla ki i ṣe ọmọ ilu Iran, bẹẹ ni ile ọlọmọọba Ọlaitan, nipasẹ eyi ti wọn fi gbe orukọ rẹ wa siwaju ijọba, ko mọ ọn ri rara
“Ki idajọ ododo le wa ati ki alaafia le wa niluu Iran, a n ke si ijọba lati maṣe yan Ọmọlọla gẹgẹ bii Oniran"
No comments:
Post a Comment