Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti kilọ pe ko si aaye fun tita ibọn ọdun ti wọn n pe ni banga, bẹẹ ni ẹnikeni to ba ra a yoo foju winna ofin.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ naa, CSP Yẹmisi Ọpalọla, fi sita lọjọ Mọnde, ọjọ kẹtalelogun oṣu kejila ọdun yii lo ti kilọ fun awọn obi ati alagbatọ lati tete jawe akiwọwọ fun awọn ọmọ wọn.
O ni yatọ si pe banga yiyin maa n ko ipaya ba awọn olugbe agbegbe ti wọn ba to yin in, o tun maa n ṣe ijamba nla fun dukia awọn araalu.
Ọpalọla ṣalaye pe ti wọn ba yin banga ni awọn ibudokọ, agbegbe ileejọsin, ileetaja, ile igbafẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ọtọ ni ibi ti ọkan awọn araalu yoo kọkọ lọ latari eto aabo ti ko kẹsẹ jari lorileede wa bayii.
Bakan naa lo ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fofin de ṣiṣe kanifa lojuu titi kaakiri nipinlẹ Ọṣun nitori awọn janduuku le lo anfaani naa lati da wahala silẹ.
Dipo ki wọn lo ojuupopo, ileeṣẹ ọlọpaa rọ wọn lati lo awọn gbọngan inawo tabi awọn ibudo ti wọn ṣe geeti yi i ka lati le ri i pe eto aabo to muna doko wa nibẹ.
O kilọ pe ẹnikẹni tabi akojọpọ awọn eeyan ti wọn ba tapa si ikilọ yii yoo foju winna ofin ijọba.
No comments:
Post a Comment