Awọn oṣiṣẹfẹyinti ti wọn pe ara wọn ni Forum of 2011/2012 Retired Public Servants nipinlẹ Ọṣun ṣe ifẹhonu han wọọrọwọ lọjọ Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kejila ọdun yii nibi ti wọn ti ke si Gomina Ademọla Adeleke lati ṣe amuṣẹ idajọ ile-ẹjọ lorii ẹgbẹrun mejidinlogun naira owo oṣu to kere ju.
Wọn ni agbekalẹ ẹgbẹrun mẹsan-an owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju nijọba ipinlẹ Ọṣun fi n san owo ajẹmọnu awọn, gbogbo ariwo ti awọn n pa ko si wọjọba leti.
Oniruuru iwe akọle ni wọn gbe lọwọ nibi ifẹhonu han naa to waye lagbegbe Ogo-Oluwa niluu Oṣogbo, lara ohun ti wọn kọ sibẹ ni pe kijọba Adeleke bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ, wọn ni ebi n pa awọn, bẹẹ ni awọn ko bẹgbẹ pe lẹyin tawọn fi oogun-oju ṣiṣẹ funjọba lọdun marunlelọgbọn.
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn adari wọn, Comrade Yẹmi Lawal, ṣe sọ fawọn oniroyin, lati oṣu kẹwaa ọdun 2017 ni kootu awọn oṣiṣẹ, Industrial Court, ti da awọn lare, ti adajọ si paṣẹ pe kijọba Ọṣun bẹrẹ sii san owo ajẹmọnu awọn pẹlu alakalẹ ẹgbẹrun lọna mejidinlogun naira.
O ni ki i ṣe igba akọkọ tawọn yoo fẹhonu han niyii, sibẹ ijọba ko da awọn lohun. O ni awọn wa lẹnu iṣẹ nigba ti Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla buwọ lu ẹgbẹrun mejidinlogun naira fun awọn oṣiṣẹ lọdun 2011, awọn oṣiṣẹ ipele kinni si ikeje bẹrẹ gbigba owo naa loṣu kẹta ọdun 2011, ṣugbọn ko ṣe ti awọn oṣiṣẹ ipele to ku titi to fi lọ.
Comrade Lawal sọ siwaju pe ijọba Oyetọla fẹẹ buwọ lu aṣẹ ile-ẹjọ ọhun, ṣugbọn nigba ti ẹnikan lara awọn sọ pe gbogbo awọn ti fontẹ lu Ademọla Adeleke gẹgẹ bii gomina ni Oyetọla ko ṣe ṣe e mọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe nigba tijọba Adeleke tun kede ẹgbẹrun lọna aadọrin naira fun awọn oṣiṣẹfẹyinti, ireti awọn ni pe gbogbo awon oṣiṣẹfẹyinti ni wọn yoo janfaani rẹ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe ṣe ni wọn fi ẹtẹ silẹ pa lapalapa, ẹgbẹrun lọna marundinlọgbọn naira nikan ni wọn kede pe yoo wa fun gbogbo awọn, ti wọn ko si sọrọ lori ibeere awọn rara.
Awọn oṣiṣẹféyinti yii waa rọ ijọba Ademọla Adeleke lati bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ, ko si bẹrẹ sii lo alakalẹ ẹgbẹrun lọna mejidinlogun naira lati san owo ajẹmọnu awọn kiakia.
No comments:
Post a Comment