IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 11 December 2024

Awọn ọmọ Ido-Ọṣun dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu, wọn ni ki Adeleke tete waa pari papakọ ofurufu ilu wọn


Agbarijọpọ awọn ọmọbibi ilu Ido-Ọṣun nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ nipinlẹ Ọṣun ti dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun bi ko ṣe faaye gba ipinnu ijọba ipinlẹ Ọṣun lati gbe ibudo papakọ ofurufu to wa niluu naa lọ si ilu Ẹdẹ.


Bakan naa ni wọn gboṣuba fun minisita fun ọrọ irinna oju ofurufu, Amofin Festus Keyamo, minisita fun ọrọ okoowo ati igbokegbodo ọkọ lori omi, Alhaji Gboyega Oyetọla, akọwe apapọ fun ẹgbẹ oṣelu APC, Dokita Ajibola Basiru, Ọmọọba Adebayọ Adeleke (Banik) atawọn lamẹẹtọ mi-in ti wọn duro lori otitọ titi ti ọrọ naa fi yanju. 


Nibi ipade oniroyin kan ti wọn ṣe lọjọ Wẹsidee niluu Ido-Ọṣun ni agbẹnusọ wọn, Ọnarebu Abiọdun Awolọla, ti sọ pe inu gbogbo awọn ọmọ ilu naa lo dun pe awọn adari naa jẹ olotitọ, ti ki i gbe sẹyin iwa to le pa ọmọnikeji lara. 


Gẹgẹ bi wọn ṣe ṣalaye, "Inu awa eeyan ilu Ido-Ọṣun dun lori erongba ijọba apapọ lati ba wa pari MKO International Airport gẹgẹ bo ṣe wa ninu lẹta ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ irinna oju ofurufu kọ, ti wọn si tun da Gomina Nurudeen Ademọla Jackson Adeleke duro pe ko gbọdọ gbe papakọ ofurufu naa lọ si ilu abinibi rẹ ni Ẹdẹ. 


"A fẹẹ sọ ọ fun atẹnumọ pe erongba ijọba Ọṣun lati gbe papakọ naa kuro ni Ido-Ọṣun jẹ eyi ti ko tọna rara, o si wa lati tẹ ifẹ-ara ẹni lọrun lai naani obitibiti owo ipinlẹ Ọṣun ti awọn ijọba Bisi Akande, Ọlagunsoye Oyınlọla, Ọgbeni Rauf Aregbẹṣọla ati Adegboyega Oyetọla ti na lori rẹ. 


"Nitori itan, a n fi idi rẹ mulẹ pe eeka ilẹ irinwo o din mẹfa ti wọn ti gba lati ọdun 1936 fun kikọ papakọ ofurufu naa lo ṣi wa nilẹ. Nitori naa, awawi lasan nijọba to wa lode l'Ọṣun n wi pe agbegbe naa ko ṣe e lo mọ ati pe awọn kan ti kọle sori ẹ. 


"Gbọnin-gbọnin ni awọn eeyan Ido-Ọṣun wa lẹyin ipinnu ijọba apapọ lati ṣewadi finnifinni nipa papakọ ofurufu naa lati le faaye gba idajọ ododo ati ibagbepọ alaafia. 


"A n ṣeleri ifọwọsowọpọ wa fun oniruuru iṣẹ idagbasoke tijọba apapọ ba dawọle ninu ilu wa. Yoo wu wa tijọba apapọ, nipasẹ ọfiisi Amofin Festus Keyamọ, ba tete ba wa parii papakọ ofurufu yii nitori oun ni ibudo akọkọ iru ẹ lorileede Naijiria ati ni Guusu Afrika. 


"Bakan naa la tun n ṣeleri ifọwọsowọpọ wa pẹlu gomina ipinlẹ Ọṣun lati ri i pe M.K.O. International Airport, Ido-Osun di eyi to pari kiakia. A n rọ gomina lati maṣe kaarẹ nipa siṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba apapọ lati jẹ ki ibudo naa tete pari lasiko. 


"A dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn duro ti wa lọna gbogbo lati ri i pe otitọ leke, itan ko nii gbagbe ipa rere ti wọn ko lori ọrọ yii"

No comments:

Post a Comment