IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 25 December 2024

Amitolu Shittu yoo gbalejo gomina mẹta, Ọọni Ifẹ ati Adelabu l'Oṣogbo, eyi lohun to fẹẹ ṣe


Gbogbo eto lo ti to bayii fun ayẹyẹ ayajọ ọgọta ọdun ti gbajugbaja ajafẹtọ-ọmọniyan nni, Oloye Amitolu Shittu, de ile aye ati ṣiṣe akojade awọn iwe ti ọlọjọ-ibi naa kọ. 


Gẹgẹ bi alaga eto ẹlẹka meji yii, Amofin Ayọ Adesanmi, ṣe ṣalaye nibi ipade oniroyin to waye niluu Oṣogbo, ọjọ Satide, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kejila ọdun yii ni ayẹyẹ ọjọọbi Amitolu, nigba ti idanilẹkọọ ati ikojade iwe yoo waye lọjọ Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kejila. 


Adesanmi ṣalaye pe ninu ile Oloye Amitolu to wa lagbegbe Aṣubiaro niluu Oṣogbo ni ayẹyẹ ti ọjọ Satide yoo ti waye nibi ti wọn yoo ti pese ounjẹ ati aṣọ fun awọn to ku diẹ kaa to fun lawujọ ti iye wọn to ẹgbẹrun marun-un. 




O sọ siwaju pe Adolak Event Hall to wa lagbegbe Old Governor's Office, Oṣogbo, ni eto ti ọjọ Sannde yoo ti waye laago mẹwaa aarọ. 


Gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babangana Umara Zulum ati Senator Surajudeen Ajibola Basiru to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii ni yoo yannayanna akori ipejọpọ naa ti wọn pe ni "People''s Value and Leadership; The Challenges of Tinubu Presidency" 


Aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ni alejo nla pataki lọjọ naa, nigba ti Dokita Zacchaeus Adedeji Adelabu to jẹ alaga Federal Inland Revenue Services ni Abuja ati Iyaafin Otunba Grace Titilayọ Tọmọri jẹ alaga ọjọ naa.


Arole Oduuduwa, Ọlọfin Adimula, Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ni Ori-ade nibi ayẹyẹ yii, awọn alejo pataki si ni gomina ipinlẹ Ekiti, Biọdun Oyebamiji, gomina ipinlẹ Kaduna, Senator Uba Sani, Dokita Solomon Arase ati Aṣiwaju Bọla Oyebamiji. 


Gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, to jẹ minisita fun ọrọ okoowo lori omi, Alhaji Gboyega Oyetọla ni yoo jẹ olugbalejo pataki nibi ayẹyẹ yii.  


Iwe oriṣirisi mẹfa to jẹ ti Oloye Amitolu Shittu ni wọn yoo ko jade lọjọ naa, Dokita Lasisi Ọlagunju ati Ọnarebu Lekan Ọlatunji ni wọn yoo ṣe atupalẹ iwe ọhun.


Adesanmi wa ke si gbogbo awọn ololufẹ ọmọbibi ilu Oṣogbo ọhun lati tete de sibi ayẹyẹ nla mejeeji yii.

No comments:

Post a Comment