IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 17 November 2024

Wọn fojuu Agboọla gbolẹ l'Ondo, Aiyedatiwa di gomina


Ọjọgbọn Ọlayẹmi Akinwunmi ti kede Ọgbẹni Lucky Aiyedatiwa gẹgẹ bii oludije to gbegba oroke ninu idibo gomina to waye nipinlẹ Ondo. 


Laarin awọn ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to kopa ninu idibo naa, Aiyedatiwa, oludije latinu egbẹ APC ni ibo 367,781, nigba ti oludije ninu ẹgbẹ PDP, Agboọla Ajayi to sunmọ ọn ni ibo 117,845.


Kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ ọhun nidibo ti waye lọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun yii, wọn si kede ẹni to jawe olubori laago meji aabọ ọsan ọjọ Sannde, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kọkanla ọdun yii. 


Aiyedatiwa ni igbakeji Gomina Ondo tẹlẹ to doloogbe, Ọgbẹni Rotimi Akeredolu, oun lo si pari saa ọkunrin naa lẹyin to jade laye. 


Ni bayii, alakoso idibo naa, Ọjọgbọn Akinwumi ti kede Aiyedatiwa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ondo.

No comments:

Post a Comment