Alaga apapọ ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress (APC), Abdullahi Ganduje, ti sọ pe lẹyin ti ẹgbẹ naa ti jawe olubori nipinlẹ Ondo bayii, ipinlẹ Ọṣun ati ipinlẹ Ọyọ lafojusun awọn.
Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn kede Lucky Aiyedatiwa ti ẹgbẹ APC gẹgẹ bii oludije to jawe olubori ninu idibo gomina to wa nipinlẹ Ondo lọjọ Satide ọjọ kẹrindinlogun oṣu yii, ni Ganduje ti dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Tinubu fun atilẹyin rẹ.
O ni oludije to tayọ awọn yooku rẹ ni Aiyedatiwa, abajade idibo naa si fihan pr awọn araalu fẹran re.
Ganduje sọ siwaju pe gbogbo awọn lamẹẹtọ ninu eto idibo naa ni wọn jẹri pe o lọ nirọwọrọsẹ lai ni eru kankan ninu. O ni wọn dibo fun itẹsiwaju iṣẹ rere nipinlẹ Ondo, ẹgbẹ naa ko si nii ja wọn kulẹ.
O waa fi da awọn eeyan loju pe ipinlẹ Ọṣun ati ipinlẹ Ọyọ lo ku ti awọn n foju sun, gbogbo igi ti elegbeje awọn ba si ti lu gbọdọ dun ni.
No comments:
Post a Comment