Ẹrin kikiki lo gba inu gbọngan igbalejo gomina to wa ninu sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọṣun lọsan oni, Furaidee, nigba ti olori awọn oṣiṣẹ ijọba, NLC, Comrade Christopher Arapaṣopo, sọ pe afi ki awọn ka ohun to wa ninu akọsilẹ owo oṣu tuntun tijọba sọ pe ki awọn buwọ lu.
Gbagede ti fi to yin leti pe awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọṣun ati ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti forikori, wọn si tu buwọ lu iwe adehun owo oṣu tuntun ti Gomina Ademọla Adeleke kede rẹ fun awọn oṣiṣẹ ijọba l'Ọṣun, iyẹn ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin naira.
Nibi ipade naa, lẹyin ti Oluọmọ Kọlapọ Alimi to jẹ kọmiṣanna fun eto iroyin yannana gbogbo nnkan to wa ninu adehun ọhun lo ke si awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ lati wa maa buwọ lu iwe adehun naa lẹyọkọọkan.
Ṣugbọn kia ni Arapaṣopo nawọ soke, o ni oun ni ọrọ lati sọ. O ni oun dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun fun igbesẹ yii, ṣugbọn ko too di pe awọn yoo buwọ lu iwe adehun naa, awọn gbọdọ ka gbogbo nnkan to wa nibẹ finnifinni.
Bayii ni igbakeji gomina, Ọmọọba Adewusi ati Oluọmọ Kọlapọ Alimi pẹlu olori awọn oṣiṣẹ ijọba, Ọgbẹni Samuel Ayanlẹyẹ Aina, sọ pe ki awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ ka iwe adehun naa, ki wọn si buwọ lu u lẹyin to ba tẹ wọn lọwọ.
Lẹyin ti wọn ka a tan, ni wọn buwọ lu u lẹyọkọọkan.
Ọmọọba Adewusi waa ke si awọn oṣiṣẹ ọhun lati mu iṣẹ wọn lọkunkundun, ki wọn si tubọ maa ṣatilẹyin fun iṣejọba Gomina Adeleke.
No comments:
Post a Comment