Pẹpẹpẹ ni obinrin kan, Adeyẹmi Adijat, n tẹwọ lagọ ọlọpaa bayii lẹyin ti awọn ọlọpaa fi ẹsun igbimọpọ lati paayan kan oun atawọn mẹta mi-in.
Ohun to ṣẹlẹ, gẹgẹ bi Gbagede ṣe gbọ, ni pe awọn ọmọdekunrin meji kan; Ogunṣọla Roqeeb ati Adewale Temitọpẹ lọ si ṣọọbu obinrin ẹni ọdun mejidinlọgọta naa ni Asunmọ Junction, Ẹdẹ nipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹfa oṣu kọkanla ọdun yii.
Aago mẹwaa alẹ kọja diẹ ni wọn debẹ, bi ọkan lara wọn ṣe n ba obinrin oniṣọọbu naa sọrọ ni ekeji n dọgbọn ji nnkan.
Wọn ji ike maltina mẹta, paali siga kan ati igo ọti Origin kan, ṣugbọn wọn ko tii rin jinna ti iya yii fi fura, to si pariwo ole le wọn.
Bayii lawọn ọkunrin ti wọn n ṣe faaji nitosi ṣọọbu naa fọn sita, wọn ri awọn ole mejeeji yii mu, wọn si lu Temitọpẹ pa loju ẹsẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe ọwọ tẹ mẹta lara awọn to pe ni tọọgi naa, awọn naa si ni Akeem Akinọla, Lamidi Abass ati Ibrahim Quadri.
Ọpalọla sọ pe dipo ki wọn fa ọmọdekunrin naa le awọn agbofinro lọwọ, ṣe ni wọn ṣedajọ lọwọ araa wọn, ti wọn lu u pa.
Ọpalọla sọ siwaju pe awọn eeyan naa yoo foju bale-ẹjọ lẹyin iwadii.
No comments:
Post a Comment