Pa Tajudeen Lagbaja, olori ẹbi ile ti wọn ti bi ọga awọn sọja lorileede yii to doloogbe, Lt. Gen. Taoreed Abiọdun Lagbaja, ti sọ pe kijọba apapọ yọnda oku ọkunrin naa fun awọn.
Laarọ oni ni oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Bọla Tinubu lori eto iroyin, Bayọ Ọnanuga, kede pe Lagbaja jade laye niluu Eko ni alẹ ọjọ Tusidee lẹni ọdun mẹrindinlọgọta.
Baba agba to sọrọ pẹlu ibanujẹ lagboole wọn sọ pe ilu abinibi ọkunrin ọhun, Ilobu nipinlẹ Ọṣun, ni yoo wu awọn ki awọn sin oku olu-ọmọ naa si.
O ni inu ibanujẹ gbaa ni iku Lagbaja jẹ fun gbogbo mọlẹbi naa, o si fẹẹ gba ẹmi toun gan-an paapaa, idi niyii ti gbogbo mọlẹbi ko ṣe fẹ ki wọn sin in siluu Abuja, ki wọn gbe e wa si Ilobu.
Olori ẹbi ṣalaye siwaju pe ọpọlọpọ eeyan lo ti ku sẹyin lagbole ọhun, sugbọn iku Taoreed Lagbaja jẹ iku ibanujẹ ati adanu fun gbogbo ẹbi ati iluu Ilobu.
No comments:
Post a Comment