Imaanu Agba fun awọn ẹlẹwọn ti wọn wa lọgba ẹwọn ilu Ileṣa nipinlẹ Ọṣun ti ke si gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati yago fun iwa ipanle to le gbe wọn de ọgba ẹwọn.
Imaamu Agba naa, ẹni ti a fi orukọ bo laṣiri, ṣalaye pe isa-oku aye ni ọgba ẹwọn jẹ, igbe-aye inu ibẹ si yatọ gedengbe si eyi ti ẹnikẹni le fi ṣadura.
Lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin Islam kan, Daaru-r-Rahmat Society of Nigeria, ṣabẹwo si ọgba ẹwọn naa lara alakalẹ eto ayẹyẹ ajọdun ọdun kẹẹdogun ti wọn da a silẹ ni Imaamu yii sọrọ naa.
O ni ohun ko mọ pe abamọ nla ni iwa ti oun n hu nigba yẹn yoo mu ba oun, afigba ti ọwọ tẹ oun lasiko ti awọn lọọ jale ni ilegbee awọn akẹkọọ niluu Iree nipinlẹ Ọṣun.
O fi kun ọrọ rẹ pe baba oun kilọ fun oun titi, ṣugbọn oun ko da a lohun, amọ nigba ti oun de ọgba ẹwọn lẹyin ti ọwọ tẹ oun nikanṣoṣo laarin ikọ ẹlẹni mẹrin tawọn jọ n jale lohun to mọ pe ohun to wa lẹyin ọfa ju èje lọ.
O ni, “Ẹ ba wa sọ fun awọn ọmọ Naijiria patapata pe ki wọn ni itẹlọrun, ki ẹ si ba wa bẹ ijọba pe ki wọn maṣe gbagbe wa sibi. Ọpọlọpọ lara wa la ti kabamọ nnkan ti a ṣe, a si ti ronu piwada.
“Lati ọdun 2008 ni mo ti wa nibi. Mo ti pari ẹkọ mi ni Open University bayii. Ọpọ lo wa nibi nitori aisi agbara lati gba agbẹjọro, ọpọ lo jale nitori ebi to n pa wọn, ṣugbọn ti wọn wa nibi. Nitori faini kekere, ọpọ ti lo ogun ọdun nibi.
“Aini itẹlọrun lo sun ọpọ wa de ọgba ẹwọn. Baba mi kilọ fun mi titi, ṣugbọn n ko gbọ. Emi nikan ni wọn ri mu laarin awa mẹrin ti a lọọ jale n'Iree lọjọ naa. Ti ori ba yọ wa nibi, a maa gbe iwa ọmọluabi wọ bii ẹwu nitori a mọ pe ẹni to ba tẹwọn de to tun lọọ jale, iku lo ku, tabi ko tun pada sẹwọn.”
Nigba to n ba awọn ẹlẹwọn naa sọrọ lẹyin ti wọn ko oniruuru ounjẹ ati aṣọ fun wọn, Ameer ẹgbẹ naa, Imam Muali Ọlawale, ẹni ti awọn ọmọ ẹgbẹ ba kọwọrin lọ sibẹ, rọ wọn lati tun igbagbọ wọn ṣe ninu Ọlọrun, ki wọn si ni ireti kikun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Mi o fẹ ki ẹ ri ibi ti ẹ wa yii bii opin irinajo yin. Ko ti i tan fun yin. Lati ibi yii, ẹ kọ iwa ọmọluabi ti ẹ fẹẹ maa hu lẹyin ti ẹ ba gba ominira. O ti wa ninu akọọlẹ pe a maa fi yin pamọ sibi fungba diẹ.
“Ẹ tun ireti ati igbagbọ yin ṣe. Ohun kanṣoṣo ti ijọba to wa lode ni Naijiria n polongo niyẹn, gbogbo nnkan yoo si dara fun wa. Ẹ mu ọkan le, ki ẹ si fẹran araa yin, ẹ maa debi giga lẹyin ti ẹ ba gba ominira nibi.”
No comments:
Post a Comment