Ọmọkunrin kan, Godwin Emmanuel lo ti wa lakolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun bayii lori ẹsun ole jija.
Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun yii lọwọ tẹ Emmanuel to jẹ ọkan lara awọn ikọ adigunjale ẹlẹni marun ọhun.
Awọn arinrinajo loju ọna Ileṣa si Oṣu lawọn eeyan yii da lọna lọjọ naa, ti wọn si gba owo, kaadi ATM atawọn nnkan mi-in lọwọ wọn.
Ọkan lara wọn to ko sọwọ awọn figilante lo taṣiri pe ilu Ikorodu nipinlẹ Eko lawọn ti wa, bẹẹ lawọn ọlọpaa si lọ sibẹ lati ko wọn.
Loju ọna Eko si Oṣogbo ni Emmanuel tun ti ji foonu ọkan lara awọn ọlọpaa, o si ti de inu sẹẹli ki awọn ọlọpaa too fura pe foonu kan ti dawati.
Bi wọn ṣe tu ara awọn afurasi naa ni wọn ba foonu lọwọọ Emmanuel.
No comments:
Post a Comment