IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 9 November 2024

Mo kabamọ pe mo gba fọọmu sọja fun Taoreed Lagbaja - Olori ẹbi


Olori ẹbi idile ọga agba awọn sọja lorileede yii to doloogbe laipẹ yii, Pa. Tajudeen Lagbaja, ti sọ pe to ba jẹ pe oun mọ pe ibi ti ọrọ Taoreed Abiọdun Lagbaja yoo ja si niyii oun i ba ti gba fọọmu fun un lati darapọ mọ sọja. 


Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu wọn, Ilobu nijọba ibilẹ Irẹpọdun nipinlẹ Ọṣun, baba agba yii ṣalaye pe oun ni aburo baba to bi Taoreed Lagbaja, oun loun si gba fọọmu sọja fun un lọdun naa lọhun. 


Baba Tajudeen fi kun ọrọ rẹ pe, ''Gbogbo ẹda ti a bi ninu obinrin lo gbọdọ ku. A fọpẹ fun Ọlọrun. To ba jẹ pe mo mọ pe yoo fi iku ṣagba mi ni, mi o ba ti gba fọọmu sọja fun un lọdun naa. Mo kabamọ pe mo gba fọọmu yẹn fun un, ṣugbọn akọsilẹ ẹda ti gbẹ


“Emi lo yẹ ki iku to pa Taoreed Lagbaja yẹn pa. Mo mu un gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ mi. O ba gbogbo mọlẹbi ninu jẹ pupọ. Gbogbo ileri to ṣe fun wa ni iku ko jẹ ko mu ṣẹ.

No comments:

Post a Comment