Alhaji Teslim Igbalaye to jẹ akọwe funjọba ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe nigba ti Gomina Ademọla Adeleke ba ṣi aṣọ lori oniruuru awọn iṣẹ akanṣe to ti ṣe laarin ọdun meji pere, yoo ṣoro fun ẹgbẹ oṣelu miran lati sọ pe awọn fẹẹ dupo gomina Ọṣun lọdun 2026.
O ni aṣeyọri ti ọpọ ijọba maa n pariwo le lori lẹyin ọdun mẹrin ni Gomina Adeleke ti ṣe laarin ọdun meji, eleyii ti ko si tii si iru akọsilẹ rẹ nipinlẹ Ọṣun.
Nibi ipade oniroyin ti wọn gbe kalẹ lati ṣalaye oniruuru eto ti wọn fẹẹ ṣe fun ayẹyẹ ọdun keji tiṣejọba Adeleke bẹrẹ l'Ọṣun ni Igbalaye ti sọ pe ko si ibi ti ti ọwọja iṣẹ idagbasoke ijọba yii ko tii de.
O ni kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Ọṣun ni awọn yoo lọ lati ṣiṣọ loju iṣẹ akanṣe tijọba yii ti ṣe ni gbogbo ẹka patapata lai yọ eyikeyi silẹ.
Lara awọn eto ti wọn la kalẹ ọhun, gẹgẹ bi Igbalaye ṣe sọ, ni ṣiṣi oju ọna alabala meji to wa lati Old Garage si Okefia niluu Oṣogbo, ṣiṣi awọn oju-ọna tijọba sọ di eyi to ṣee rin kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn nipinlẹ Ọṣun.
O ni isin idupẹ yoo waye ni mọṣalaaṣi ati ṣọọṣi, wọn yoo gba bọọlu alawada, ijọba yoo fun awọn oṣiṣẹfẹyinti onimọdamọda ni obitibiti owo, wọn yoo si fi orukọ awọn akanda-ẹda silẹ lọfẹẹ labẹ eto ilera adojutofo.
Igbalaye sọ siwaju pe wọn yoo fi ami-ẹyẹ da ọpọlọpọ awọn ọmọbibi ipinlẹ Ọṣun ti wọn ti fakọyọ nidi oniruuru iṣẹ ti wọn yan laayo lọla; yala, wọn ti doloogbe tabi wọn ṣi wa laye.
Bakan naa ni Adeleke yoo ba awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun sọrọ laarọ ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla, nigba ti ipade apero yoo waye nibi ti awọn araalu yoo ti lanfaani lati fojurinju pẹlu gomina wọn.
No comments:
Post a Comment