IROYIN YAJOYAJO

Friday, 29 November 2024

Iroyin Ayọ: Adeleke kede ọjọ ti sisan owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ


Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede pe ọjọ kinni oṣu kejila ọdun yii ni sisan owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ rẹ yoo bẹrẹ.

Ijọba Ọṣun ti kede pe oṣiṣẹ to kere ju yoo maa gba ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin naira gẹgẹ bii owo oṣu tuntun.

Nibi ipade kan tijọba ṣe pẹlu adari awọn oṣiṣẹ lati bu ọwọ lu adehun naa ni kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, ti sọ pe agbekalẹ owo oṣu tuntun naa yoo bẹrẹ ninu owo oṣu kọkanla tawọn oṣiṣẹ yoo gba.

Bakan naa nijọba kede pe afikun ẹgbẹrun lọna mẹẹdọgbọn Naira yoo gun owo gbogbo awọn oṣiṣẹfẹyinti l'Ọṣun.

1 comment:

  1. Iroyin idunu fun awon osise sit gbogbo Omo ipinle Osun lapapo Imole deeeeeeeeee oooooooooooo

    ReplyDelete