IROYIN YAJOYAJO

Monday, 18 November 2024

Ika ni ẹgbẹ oṣelu APC, wọn ko yatọ si awọn boko haraamu - PDP


Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti sọ pe ko si iyatọ kankan laarin ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) pẹlu awọn ikọ agbesunmọmi ati boko haraamu ti wọn n ta awọn araalu bii tamọ-tiye. 


Ẹgbẹ PDP ṣalaye pe, bii iṣe awọn boko haraamu, ṣe ni ẹgbẹ APC n pin idaamu, ibanujẹ, ẹkun ati ipayinkeke kaakiri ibi ti wọn ba ti lanfaani lati gba. 


Adele akọwe ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọỵọ, Ọgbẹni Micheal Ogunṣina lo sọrọ yii lasiko to n fesi si ọrọ ti alaga apapọ ẹgbẹ APC, Dokita Abdullahi Ganduje sọ laipẹ yii pe ipinlẹ Ọṣun ati Ọyọ lo ku ti ẹgbẹ naa yoo gba lẹyin ti wọn ti gba Ondo bayii. 


Ogunṣina ṣalaye pe gbogbo ọmọ Naijiria kaakiri ni wọn n gbadura kikankikan pe inira ti ẹgbẹ APC n ko ba wọn gbọdọ dopin loṣu karun ọdun 2027.


O ni ohun ti Ganduje sọ kan wu u lasan ni, ala ti ko le ṣẹ ni. O ni gbogbo aye lo ri iwa ainitiju ti wọn hu L'Ondo lasiko idibo naa, ṣugbọn ilẹ yoo mọ ba wọn laipẹ. 


Gẹgẹ bo ṣe sọ, itiju ati iyalẹnu nla lo jẹ pe nigba ti awọn adari ẹgbẹ APC n ṣe ọkanjua lati gba ipo agbara, gbogbo wakati ni ojuko ti wọn ti n pin ina ijọba lorileede yii n daku-daji. Bawo wa ni wọn ṣe lẹnu lati sọrọ lori idibo? 


'Dipo ki wọn mojuto bi wọn yoo ṣe fopin si inira ti wọn mu ba araalu, bi wọn a ṣe gba gbogbo ipinlẹ lo wa lọkan wọn, ki wọn si tẹ ori gbogbo aye ba si abẹ itisẹ wọn. 


“O ti su gbogbo araalu, ki Ganduje atawọn ikọ rẹ ti wọn jọ n pinnu lati gba ipinlẹ Ọyọ tete sa fun ibinu Ọlọrun, ika ni wọn, a kọ̀ wọn patapata, Ọlọrun to si korira awọn ika ti ba wa kọ̀ wọn. O to gẹẹ”

No comments:

Post a Comment