IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 7 November 2024

Idi ti igbalẹ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun fi n yọ lẹyọkọọkan lojoojumọ - Sunday Bisi


Alaga ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP, nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Sunday Bisi, ti sọ pe oniruuru iṣẹ idagbasoke ti Gomina Ademọla Adeleke, n ṣe lojoojumọ lo fa a ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako fi n rọ kẹtikẹti wọ inu ẹgbẹ naa bayii. 


Nigba to n fesi si abajade iwadii ajọ kan to maa n tọpintọpin eto idibo, eleyii to ni ibaṣepọ pẹlu Fasiti Ifẹ, iyẹn, Democracy Polling Agency, ninu eyi ti wọn ti sọ pe ẹgbẹ PDP Ọṣun ti fi ida aadọta ninu ọgọrun-un le si iye ti awọn ọmọ naa jẹ tẹlẹ, ni Bisi ṣalaye pe mariwo ni wọn ri, eegun ṣi n bọ lẹyin. 


O fi kun ọrọ rẹ pe ki awọn ajọ naa ma mikan lori ohun ti wọn sọ pe o ṣee ṣe ki ija waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ to wa nibẹ tẹlẹ atawọn ti wọn ṣẹṣẹ n darapọ. 


Sunday Bisi ṣalaye pe ẹgbẹ naa ni eto iṣakoso to duroore lọjọkọjọ lati dena ohunkohun to le fa aawọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ wọn; yala awọn to ti wa ninu ẹgbẹ tabi awọn to ṣẹṣẹ n darapọ mọ wọn. 


O ni ko si eyi to ṣe e gbe pamọ ninu awọn iṣẹ meriiri ti Gomina Adeleke n ṣe bayii nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni ko si si gomina to ṣeruu rẹ ri laarin ọdun meji pere. 


Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn ẹgbẹ alatako, paapaa, igun ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn pe ni Ileri Oluwa, ko lee sọ pe nnkan firi lawọn n ri bayii, idi si niyẹn ti wọn fi n ju igbalẹ silẹ, ti wọn n wọnu ẹgbẹ PDP. 


O waa fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe gbagada ni ilẹkun ẹgbẹ naa ṣi silẹ lati tubọ gba awọn ti wọn ba tun fẹẹ tẹlẹ reluwee idagbasoke to n lọ kaakiri ipinlẹ Ọṣun bayii labẹ asia ẹgbẹ PDP.

No comments:

Post a Comment