Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede pe wọn yoo ṣe ifilọlẹ ibudo tuntun fun papakọ ofurufu ipinlẹ Ọṣun loṣu kejila ọdun yii.
Alaga fun eto ayẹyẹ ọdun keji iṣejọba Gomina Ademọla Adeleke, Alhaji Teslim Igbalaye, lo sọrọ naa ninu ipade oniroyin.
Igbalaye ṣalaye pe ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ti kọle sorii ilẹ ibudo ti wọn fẹẹ lo tẹlẹ to wa ni Ido Ọṣun, tijọba ba si fẹẹ maa wo awọn ile naa, yoo na ijọba lọwọ pupọ.
Ni bayii, o ni wọn ti gbe papakọ ofurufu naa lọ si ọna Ọlọdan nitosi Aiṣu niluu Ẹdẹ.
No comments:
Post a Comment