IROYIN YAJOYAJO

Friday, 29 November 2024

Gomina Adeleke fọwọ si yiyan ọba tuntun fun ilu Ido-Ọṣun


Gomina Ademọla Adeleke ti fọwọ si orukọ Ọmọọba Jokotọla Ọlayinka Tunde gẹgẹ bii Olojudo tuntun fun ilu Ido-Ọṣun.

Ọjọ kẹtadinlogun oṣu karun ọdun yii ni Olojudo tẹlẹ, Ọba Aderẹmi Adedapọ, darapọ mọ awọn babanla rẹ.

Nibi ipade ọmọ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ọṣun ni Adeleke ti sọ pe lẹyin gbogbo ilana aatẹle, ti awọn afọbajẹ si yan ọkunrin naa nijọba fọwọ si orukọ rẹ.

O waa ke si Olojudo tuntun lati ṣiṣẹ fun alaafia ati idagbasoke ilu naa.

No comments:

Post a Comment