IROYIN YAJOYAJO

Friday, 15 November 2024

Eyi ni iye awọn eeyan ti mo ti pa lẹyin ti Bọde Itaapa mu mi wọnu ẹgbẹ okunkun - Saheed


Ọkunrin kan, Bakare Saheed, ẹni ọdun mejilelọgbọn ti sọ pe lootọ loun jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ave Confraternity labẹ idarii Owoẹyẹ Ọlabọde ti gbogbo eeyan mọ si Bọde Itaapa. 


Saheed, ti inagijẹ rẹ n jẹ Ewe, ṣalaye fun Gbagede pe Bọde Itaapa, Bisi Iwara, Solo Iwara ati Allen J to ti doloogbe bayii ni wọn ṣagbatẹru bi oun ṣe di ọmọ ẹgbẹ okunkun naa lọdun 2014, ti oun si n ba wọn ṣiṣẹ kaakiri 


O ṣalaye pe ọdun 2020 loun pa eeyan kanṣoṣo ti oun pa ri, orukọ rẹ si ni Tafa. O ni Bọde Itaapa lo fun oun ni ibọn pe ki oun lọ jiṣẹ iku fun Tafa to jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, nigba ti oun si pa a tan, oun da ibọn pada fun Bọde. 


Nigba to n sọ bi ọwọ ṣe tẹ Saheed, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe latigba ti ọwọ ti tẹ Bọde Itaapa ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to wa niluu Itaapa ti sa lọ si ilu Igangan. 


Ọpalọla sọ siwaju pe ọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun yii ni awọn eeyan agbegbe naa fi to ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti iwa ijinigbe leti nipa ọsẹ ti Saheed n hu nibẹ. 


Gbogbo igi onigi lagbegbe naa ni wọn ni Saheed maa n ge, ti yoo si dunkoko mọ awọn oloko pe yala ki wọn fi oko wọn silẹ tabi ki wọn fi ẹmi ara wọn di i. 


Ọpalọla sọ pe Saheed yoo foju ba kootu lẹyin iwadi.

No comments:

Post a Comment