IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 7 November 2024

Adeleke kede ọjọ mẹta lati fi ṣọfọ Lagbaja, o ni ọkan lara ogo ipinlẹ Ọṣun ni


Gomina Ademọla Adeleke ti kede ọjọ mẹta lati fi ṣe idaro olori awọn sọja lorileede yii, Ọgagun Taoreed Abiọdun Lagbaja, to jade laye lọjọọ Tusidee ọjọ karun-un oṣu kọkanla ọdun yii. 


Ninu atẹjade kan ti kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, fi sita, ọjọ iṣọfọ naa yoo bẹrẹ lonii ọjọ Tọsidee, ọjọ keje, titi di ọjọ Satide, ọjọ kẹsan-an oṣu kọkanla. 


Bakan naa ni gomina paṣẹ pe ki wọn fa asia orileede yii si agbedemeji kaakiri ipinlẹ Ọṣun lati fi bu ọla fun Lagbaja, ọmọbibi ilu Ilobu nijọba ibilẹ Irẹpọdun nipinlẹ Ọṣun to ku lẹni ọdun mẹrindinlọgọta ọhun.  


Atẹjade naa ṣalaye pe ijọba ti gbe iwe kan kalẹ nilegbee gomina ati ni sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọṣun lati fun awọn ti wọn ba fẹẹ kọ ọrọ ibanidaro nipa ọkunrin naa, ẹni to jẹ ọkan lara awọn ogo ipinlẹ Ọṣun. 


Gẹgẹ bi Alimi ṣe sọ, iku Lagbaja jẹ ibanujẹ nla fun orileede yii ati fun iran ọmọniyan, manigbagbe si ni awọn ipa to ko nigba aye rẹ. 


Wọn waa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ọkunrin naa si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment