IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 7 November 2024

Adeleke, inira yii pọ o, san owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ ijọba - TOM


The Osun Masterminds, TOM, ti ke si Gomina Ademọla Adeleke lati bẹrẹ sisan owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ ijọba ki ara le tu gbogbo araalu. 


Nibi ipade oniroyin oloṣooṣu ti ẹgbẹ naa ṣe niluu Oṣogbo ni alakoso rẹ, Ọjọgbọn Wasiu Oyedokun-Alli, ti sọ pe ijọba apapọ ati awọn ijọba ipinlẹ ko ṣe to lati din idaamu ti awọn araalu n koju lasiko yii ku. 

O ni tijọba apapọ ba kan tiẹ kọ iha kokanmi si ilakọja awọn araalu, eewo ni ti awọn ijọba ipinlẹ ti wọn n gba owo nlanla latọdọ ijọba apapọ bayii. 

TOM ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ọṣun pe ijọba Gomina Adeleke ko sọ nnkan kan lori ọrọ owo-oṣu awọn oṣiṣẹ to kere ju, iyẹn ẹgbẹrun lọna aadọrin naira, tijọba apapọ kede laipẹ yii. 

O ni pupọ awọn ipinlẹ ni wọn ti kede iye ti wọn lagbara lati san, ṣugbọn dipo ki Adeleke kede tiẹ, biriiji lo n ṣe kaakiri awọn agbegbe ti ko niloo biriiji, ti ebi si n pa awọn araalu. 

Ẹgbẹ naa ran ijọba leti pe ti aye ba ti gbẹdẹmukẹ fun awọn oṣiṣẹ ijọba, o di dandan ko ran awọn araalu, bẹrẹ latọdọ awọn iyalọja ati oniṣowo kekeke. 

TOM waa gboṣuba fun ijọba Adeleke lori igbesẹ bo ṣe fofin de awọn ọkọ nlanla lati maṣe gun orii biriiji abẹyẹfo orita Ọlaiya niluu Oṣogbo mọ, ṣugbọn o bu ẹnu atẹ lu bijọba ṣe gbe ọrọ naa kalẹ eleyii to yọri si ede aiyede laarin ijọba atawọn ẹgbẹ oṣelu alatako. 

Bakan naa ni wọn ke si awọn ti wọn wa nijọba lati mọ pe oju lo pẹ si, eegun yoo pada di eeyan, ki wọn din ina apa ku, ki wọn si lo owo to n wọle sasunwọn ijọba fun idagbasoke agbegbe. 

No comments:

Post a Comment