Pẹlu bi owo gbogbo nnkan ṣe n fojoojumọ gbẹnusoke lorileede yii bayii, ọkunrin oṣere tiata kan, Chiwetalu Agu, ti ranṣẹ ikilọ fawọn ọkunrin lati yago fun fifun obinrin loyun.
Ninu ọrọ to gbe jade lori ikanni istagraamu rẹ lo ti ni asiko ti onikaluku gbọdọ mọ iwọn ara rẹ la wa bayii ni Naijiria.
Yatọ si eleyii, o tun to nnkan mẹfa miin silẹ ti gbogbo eeyan gbọdọ yago fun lasiko yii.
Agu ṣalaye pe 'Ma ṣe nnkan to le mu ọ ṣaisan, ma ṣe nnkan to le gbe ọ de ọgba ẹwọn, ri i daju pe o ni data lorii foonu rẹ lati fi mọ nnkan to n lọ lori ẹrọ ayelujara, maa mu omi daadaa, ki o si jẹ ounjẹ to faralokun, maa gbadura nigba gbogbo'
No comments:
Post a Comment