IROYIN YAJOYAJO

Friday, 11 October 2024

PDP: Ko Le Si Alaafia Nipinlẹ Rivers, Afi...- Ọmọọba Ọdẹyẹmi


Igbakeji alukooro apapọ tẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party lorileede, Ọmọọba Diran Ọdẹyẹmi, ti sọ pe ọrọ wahala ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Rivers kọja ede aiyede laarin Gomina Fubara ati Nyesom Wike. 


Ọdẹyẹmi ṣalaye pe erongba igbakeji aarẹ orileede yii nigba kan ri, Atiku Abubakar lati ṣe aarẹ Naijiria lọdun 2027 lo n da wahala naa silẹ. 


Nibi eto ifọrọwerọ kan ti League of Veteran Journalists nipinlẹ Ọṣun ṣagbekalẹ rẹ ni Ọdẹyẹmi ti ṣalaye pe awọn ti wọn ri gomina ana nipinlẹ naa, Nyesom Wike, gẹgẹ bii ọta Atiku ni wọn ni ki Fubara maa jo lọ. 


O ni igba ti Atiku ba too bọ sita kede pe oun yọwọyọsẹ ninu erongba lati ṣe aarẹ lọdun 2027 ni alaafia yoo to pada sipinlẹ Rivers nitori awọn alatilẹyin Wike ati Fubara ti gbẹ koto ọtẹ naa jin ju bo ṣe yẹn lọ. 


Ọdẹyẹmi, ẹni to jẹ alaga igbimọ to n ṣakoso Osun State College of Technology to wa niluu Ẹsa-Oke nipinlẹ Ọṣun fi kun ọrọ rẹ pe Atiku ati Wike gbọdọ ri araa wọn gẹgẹ bii aṣaaju pataki ninu ẹgbẹ PDP, ki wọn si gba alaafia laaye. 


O ni to ba to di pe awọn ọmọ ẹgbẹ n pin si meji, ti onikaluku si n to sẹyin adari to wu u, ewu nla ni, ko si le si alaafia. 


Ni ti ipinlẹ Ọṣun, Ọdẹyẹmi ṣalaye pe ojoojumọ lawọn oloṣelu ti wọn nitumọ n darapọ mọ ẹgbẹ PDP nitori oniruuru iṣe ribiribi ti Gomina Adeleke n ṣe ati pe awọn ti wọn n kuro ninu ẹgbẹ ko le ni ipa kankan lori idibo ọdun 2026.

No comments:

Post a Comment