IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 17 October 2024

Osun 2026: Oyetọla ni oludije ti a maa fa kalẹ, ayafi.... - Oluọmọ Akere

Okan lara awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ọṣun,


Oluọmọ Sunday Akere, ti sọ pe Alhaji Gboyega Oyetọla ni ẹgbẹ oṣelu naa maa fa kalẹ gẹgẹ bii oludije funpo gomina lọdun 2026.


Akere, ẹni to sọrọ yii niluu Oṣogbo, ṣọ pẹlu idaniloju pe Oyetọla yoo fidi Gomina Ademọla Adeleke janlẹ ninu idibo naa.


O ni ẹni akọkọ to ni ẹtọ lati jade gẹgẹ bii oludije ni Alhaji Oyetọla nitori oun ni oludije awọn lọdun 2022, ayafi to ba sọ pe oun ko dupo naa lo ku.


Akere sọ siwaju pe awọn alagbara kan ti wọn wa nijọba apapọ lọsun 2022 ni wọn lẹdi apo pọ mọ awọn oṣiṣẹ alaabo atawọn ti ọrọ idibo kan lati dabaaru idibo ọdun naa.


O ni ki i ṣe pe awọn ara ipinlẹ Ọṣun korira Oyetọla, ṣugbọn ṣe lawọn ti wọn ṣiṣẹ naa ro pe ti awọn ko ba jẹ ki Oyetọla di gomina Ọṣun, yoo nira fun Aṣiwaju Bọla Tinubu lati di aarẹ orileede yii.


Akere sọ siwaju pe gbogbo awọn araalu ni wọn ti ri iyatọ bayii, nigba ti asiko idibo ba si to, oniruuru aṣiri ni yoo jade, ti ẹgbẹ APC yoo si le ẹgbẹ PDP lugbo l'Ọṣun.

No comments:

Post a Comment