IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 20 October 2024

Osun 2026: Gomina Adeleke ko nilo lati polongo ibo, iṣẹ rẹ ni yoo polongo fun un - Oyewumi


Igbakeji olori awọn ọmọ ile to kere ju nile igbimọ aṣofin apapọ orileede yii, Sẹnetọ Lere Oyewumi, ti sọ pe, ko ni wa ka tẹ ninu, iṣẹ rere Gomina Ademọla Adeleke l'Ọṣun ti fun un ni tikẹẹti lati ṣe saa keji. 


Oyewumi, aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-oorun Ọṣun, ṣalaye ọrọ yii niluu Ikire lọjọ Satide lasiko to n gba ogunlọgọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lagbegbe naa sinu ẹgbẹ PDP. 




O ni ko si ẹni ti wọn fipa mu ninu awọn ọmọ ẹgbẹ APC tẹlẹ ọhun, ṣe ni gbogbo wọn kan ri i pe iku ko ṣee fi we oorun, ajanaku kọjaa mo ri nnkan firi ni ohun ti Adeleke ti ṣe laarin ọdun meji pere. 


 Aṣofin yii sọ siwaju pe gbogbo bi awọn oloṣelu ti wọn nitumọ l'Ọṣun ṣe n sa kuro ninu ẹgbẹ APC sinu ẹgbẹ PDP bayii fi han pe ọna ti la peregede fun Gomina Adeleke lati du saa keji lọdun-un 2026.


Gẹgẹ bo ṣe wi, ''Kaakiri ijọba ibilẹ Irewọle lawọn eeyan yii ti wa. Awọn eeyan ti dan ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress wo, bẹẹ ni wọn mọ nnkan ti wọn n ri lati ọdọ Peoples Democratic Party bayii, nitori naa, ko nilo keeyan maa daamu polongo ka. 




''Funra awọn araalu ni wọn yoo sọ eyi ti wọn fẹẹ tẹle laarin ẹgbẹ oṣelu mejeeji yii lasiko idibo gomina ọdun un 2026.


"Awọn ti wọn n ṣekawọ agbegbe wọn gẹgẹ bii oloṣelu lẹ n wo yii o. Oluọdẹ ilu Ikire wa nibi, oun tun ni igbakeji awọn ọlọdẹ nipinlẹ Ọṣun, awọn to si n ṣakoso lagbegbe rẹ ko kere rara. 


"Adeleke ti polongo ibo saa keji funraarẹ lai tii lo ọdun meji lori aleefa. Niluu Ikire lasan, o ti da ọna onikilomita marun-un pari, iṣẹ si n lọ lori awọn ọna yooku. O ti tun awọn ileewosan alabọọde meje ṣe, bẹẹ ni awọn yaara ikawe ni girama ati alakọbẹrẹ ko lounka. 


"Kanga igbalode wa kaakiri awọn wọọdu wa, bẹẹ ni eto iwosan ọfẹ loorekoore ko duro. Awa ki i ṣe alaimoore nijọba ibilẹ Irewọle, a si ti ṣetan lati san ere awọn iṣẹ yii fun gomina lasiko idibo to n bọ. 


Ṣaaju ni alaga ẹgbẹ PDP l'Ọṣun, Ọgbẹni Sunday Bisi, ti gboṣuba fun awọn ti wọn darapọ mọ wọn ọhun, o si ṣeleri pe ẹgbẹ naa ti ṣetan lati jẹ ki gbogbo wọn ri ere jijẹ ọmọ ẹgbẹ to ni imọlara ilakọja awọn araalu.

No comments:

Post a Comment