Kaakiri origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti n ba Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladọja, kẹdun pẹlu bo ṣe padanu ọkan ninu awọn aya rẹ, Tinuade Ladọja.
Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni iya naa j’Ọlọrun nipe lẹyin ailera ranpẹ.
Abilekọ Tinuade to doloogbe yii ni iyaale patapata fun awọn olorì Ọba Ladọja, nitori oun niyawo ti Ọtun Olubadan, to ti figba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ naa kọkọ fẹ.
Ọdun mọkanlelaaadọrin (71) niya naa lo loke eepẹ kọlọjọ too de.
Ọkan pataki ninu ijọ Celestial Church of Christ, lobinrin naa jẹ nígbà ayé ẹ, nitori ọmọ igbimọ awọn oluṣọ-agutan ijọ naa ni i ṣe.
Akọwe iroyin fun Ọba Ladọja, Ọgbẹni Adeọla Ọlọkọ, lo kọkọ fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ n’Ibadan.
Bakan naa ni igbimọ alakooso ijọ Ṣẹlẹ to wa ni ẹkun Kin-in-ni, ni Ikẹja, nipinlẹ Eko, nibi ti oun funra rẹ ti n ṣe ijọsin, fidi iku ẹ mulẹ lori ẹrọ ayelujara.
Gẹgẹ bi wọn ṣe kede iku ọmọ ijọ wọn pataki yii, awọn adari ijọ naa kọ ọ sori ẹrọ ayelujara pe, “Iṣẹ ọwọ Ọlọrun lawa eeyan jẹ, awa kọ la da ara wa, ara to ba si wu U lo le fi wa da, nitori aguntan rẹ lasan la jẹ.
“A ti gba fun Ọlọrun lori ohun to sẹlẹ yii. O digba o”.
No comments:
Post a Comment