IROYIN YAJOYAJO

Friday, 11 October 2024

O Ma Se o! Lẹyin Oṣu Mẹfa, Iyawo Oluṣọ Ti Ẹfanjẹliisi Rẹ Gun Pa N'Ileefẹ Jade Laye


Iyawo Pasitọ Morris Ọlagbaju Fadehan, oluṣọ ijọ Sẹlẹ ti ẹfanjẹliisi rẹ gun pa loṣu keji ọdun yii, Arabinrin Ajibọla Fadehan, ti jade laye. 


A gbọ pe aisan ranpẹ lo ṣe obinrin to jẹ ẹlẹri akọọkọ ninu ọrọ iku ọkọ rẹ ọhun, laarin ọsẹ meji si ni aisan naa to fi di pe o jade laye loṣu kẹsan ọdun yii nileewosan kan niluu Ileefẹ. 


Tẹ o ba gbagbe, Fadehan ni pasitọ ijọ Celestial Church of Christ, Grace of Comfort Parish, Omitótó ni Ilode niluu Ileefẹ, ẹni ti igbakeji rẹ. 


 Ọjọ Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keji ọdun yii ni ẹfanjẹliisi rẹ, Lekan Ogundipẹ, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Ọmọ Lefi, ṣeku pa a ninuu ṣọọṣi ọhun, to si tun dana sun oku rẹ.  


Gẹgẹ bi Gbagede ṣe gbọ, gbogbo igba ni ede-aiyede maa n waye laarin awọn mejeeji, ṣugbọn ti awọn agbaagba ijọ  maa n ba wọn yanju ẹ. 


Ṣugbọn laaarọ ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keji, Oluṣọ Fadehan lọ si ṣọọṣi, ko mọ pe Lekan ti wa nitosi, bo ṣe fori balẹ lorii pẹpẹ ni Lekan yọ si i pẹlu ibinu, ko too pariwo orukọ rẹ lẹẹmeji, Lekan ti yi aṣọ orii pẹpẹ mọ ọn lori. 


O wọ ọ kuro nibi pẹpẹ, o la aago mọ ọn lori, o si bẹrẹ si i fi ọbẹ ti wọn fi maa n tun abẹla ṣe gun un ni gbogbo ara, bo tun ṣe ri irinṣẹ (screw driver) ti wọn fi maa n tun jẹnẹretọ ṣe, lo tun fi iyẹn gun un nimu. 


Bayii lo ko awọn aṣọ to ri nitosi le oluṣọ lori, o fi aṣọ kan fa bẹntiroolu latinuu jẹnẹretọ, o da a le e lori, o si ṣana si i. 


Funraa Lekan la gbọ pe o bẹrẹ si i pe awọn ọmọ ijọ ti ile wọn ko jinna si ṣọọṣi pe ki wọn maa bọ, ina n jo lara olusọ. O tun lọ silee ẹni to da ṣọọṣi silẹ, o sọ nnkan kan naa fun un. 


Baba oludasilẹ tẹle Lekan lọ sinuu ṣọọṣi, ọkan lara awọn to pe lo waa ṣakiyesi pe oju eekanna wa lọrun rẹ, bẹẹ ni ẹjẹ wa lara aṣọ to wọ. Ọkunrin yii lo sọ fun oludasilẹ atawọn ti wọn wa nibẹ pe oun fura si Lekan. 


Wọn ti i mọnuu mọto oludasilẹ titi de awọn ọlọpaa fi de, koda, awọn ti wọn wa layika ti fẹẹ fiya jẹ Lekan, wọn fọ gilaasi mọto ti wọn gbe e sinu ẹ, agidi si lawọn ọlọpaa fi gbe e lọ. 


Amọ ṣa, agọọ ọlọpaa ni Lekan ti jẹwọ pe oun loun pa Oluṣọ sinuu ṣọọsi, ti oun si dana sun un. O ti foju bale-ẹjọ lori ọrọ naa, ti adajọ si ti paṣẹ pe ko maa naju lọgba ẹwọn ilu Ileefẹ. 


Inu oṣu kẹrin ọdun yii ni wọn sinku Pasitọ Fadehan si ile rẹ to wa ni Ìlóròmú Quarters niluu Ileefẹ, ibẹ naa la gbọ pe wọn sinkuu iyawo rẹ, Ajibọla, si loṣu kẹsan ọdun yii.

No comments:

Post a Comment