IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 19 October 2024

Lẹyin irinajo ọlọsẹ meji soke-okun, Tinubu pada si Naijiria


Aarẹ Tinubu la gbọ pe o ti pada sorileede Naijiria bayii lẹyin irinajo ọlọsẹ meji to ṣe soke-okun. 


Tinubu, ẹni to lo asiko isinmi ọlọdọọdun rẹ lati rinrinajo naa la gbọ pe o de orileede UK, Paris ati France. 


Nibẹrẹ ọsẹ yii ni awuyewuye n lọ kaakiri pe ko lẹtọọ bi aarẹ ati igbakeji rẹ, Shetimma, ṣe fi orileede Naijiria silẹ nigba kannaa. 


Amọ ṣa, ọkan lara awọn abẹṣinkawọ Tinubu, Dada Oluṣẹgun lo fi si ori ikanni tuita rẹ laipẹ yii pe aarẹ ti de. 


O kọ ọ sibẹ pe 'Kaabọ pada sile, Ọgbẹni Aarẹ. Ẹyẹ-idi ti de'


Papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe ni wọn ti ki Tinubu kaabọ si Naijiria.

No comments:

Post a Comment