IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 3 October 2024

Gbogbo araalu lo ti mọ pe ijọba to fẹ imugbooro eto ọrọ-aje ni Gomina Adeleke n ṣe l'Ọṣun - Hon. Samson Adewale


Oluranlọwọ agba pataki fun Gomina Ademọla Adeleke lori ọrọ opopona, Ọnarebu Adedayọ Samson Adewale, ti sọ pe kedere lo han bayii pe ijọba to ni erongba fun imugbooro ọrọ-aje lo wa l'Ọṣun. 


O ni bi atunṣe awọn oju-ọna ati ṣiṣe oju-ọna si awọn ibi ti ko si tẹlẹ lati le mu irinkerindo okọ rọrun ni tibutooro ipinlẹ Ọṣun ṣe jẹ Gomina Adeleke logun fi han pe ẹni to ni imọlara ilakọja awọn araalu ni. 


Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Oṣogbo laipẹ yii lori awọn ipa ti oniruuru iṣẹ akanṣe oju-ọna to n lọ lọwọ bayii kaakiri nipinlẹ Ọṣun yoo ni lori eto ọrọ-aje, Hon. Adewale ṣalaye pe ohun ti ko ṣẹlẹ ri lori atunṣe awọn oju-ọna lawọn araalu n ni iriri rẹ bayii. 


O ni yatọ si pe awọn oju-ọna naa yoo ṣanfaani fun awọn agbẹ lati ko ere-oko wọnu ilu pẹlu irọrun, yoo tun jẹ ki irinkerindo ọkọ lati ilu kan si omiran rọrun. 


Adewale fi kun ọrọ rẹ pe ọpọlọpọ awọn agbegbe ti ko sẹni to ronu pe ọna yoo debẹ lo ti n yọ kululu bayii nitori gomina mọ pe iṣẹ agbẹ yoo dun un ṣe ti awọn oju-ona ba ti dara, yoo si mu ki owo ounjẹ walẹ. 


Gẹgẹ bo ṣe wi, ṣe ni inu awọn awakọ n dun bayii nitori ko si ṣiṣe atunṣe ọkọ wọn lemọlemọ mọ, bẹẹ ni wọn ti n fi iṣẹju perete rin awọn agbegbe ti wọn n fi ọpọ wakati rin tẹlẹ. 


Nigba to n sọrọ lori idi tijọba ko fi gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de ẹgbẹ awọn awakọ NURTW, Ọnarebu Adewale ṣalaye pe ijọba apapọ ni ẹgbẹ naa n pawo fun, to si jẹ pe oju-ọna tijọba Ọṣun fi owo araalu ṣe ni wọn n lo. 


O ni latigba tijọba ti ṣagbekalẹ awọn Tranṣort Management, ọpọ anfaani nijọba ti ri nibẹ nitori o mu ki owo to n wọle labẹnu funjọba rugọgọ si i, ti ijọba si n lo awọn owo yii fun idagbasoke ipinlẹ Ọṣun.

No comments:

Post a Comment