IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 19 October 2024

Ẹ lọọ fọkanbalẹ! Laipẹ ni Gomina Adeleke yoo kede iye owo-oṣu oṣiṣẹ to kere julọ l'Ọṣun - Alimi


Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọṣun, Oluọmọ Kọlapọ Alimi, ti sọ pe igbimọ ti Gomina Ademọla Adeleke gbe kalẹ lati ṣiṣẹ lorii ọrọ owo-oṣu ti oṣiṣẹ to kere julọ yoo maa gba, iyẹn Minimum Wage, yoo pari iṣẹ wọn laipẹ. 


Nigba to n fesi si oniruuru iroyin to n lọ kaakiri lori ọrọ naa ni Alimi ṣalaye pe igbimọ naa ti ṣe ohun gbogbo finnifinni, abajade wọn ti yoo si di mimọ laipẹ yii yoo jẹ eyi to gbounjẹ fẹgbẹ. 


O ni ojuṣe igbimọ naa ni lati mu aba wa fun ijọba lori ọrọ iye ti yoo jẹ owo-oṣu oṣiṣẹ to kere julọ latari aṣẹ tuntun tijọba apapọ pa lori ẹ. 


Tẹ o ba gbagbe, atẹjade lati ọdọ olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun, Alagba Ayanlẹyẹ Aina, sọ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun fi olori awọn oṣiṣẹ lọọfiisi gomina, Alhaji Kazeem Akinlẹyẹ, ṣe alaga igbimọ naa, nigba ti alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ, Comrade Arapaṣopo Abimbọla Christopher, ko awọn oṣiṣẹ sodi nibe. 


Awọn yooku ni awọn kọmiṣanna fun eto iṣuna, eto iroyin ati ti bọjẹẹti, awọn akọwe agba diẹ, oluṣiro owo agba, darẹkitọ nileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. 


Lara awọn oṣiṣẹ ijọba to wa ninu igbimọ ọhun ni Comrade Bimbo Fasasi; Comrade Lasun Akindele; Comrade Kehinde N. Ogungbangbe; Comrade Victor Amusan; Comrade Emmanuel Olawuyi; Comrade Abdullateef Babatunde; Comrade Akinjide Akinlami; Comrade Ojo Akintunde; Comrade Akeem Adekunle; Comrade Johnson Adegoke; Comrade Ganiyu Salawu; Comrade Waheed Oyeyemi; ati Comrade Adeniran Lekan.


Alimi sọ siwaju pe gbogbo nnkan to ba jẹ abajade iṣẹ igbimọ naa ni Gomina Adeleke yoo fọwọ si nibamu pẹlu afojusun ẹlẹka-marun iṣejọba rẹ.

No comments:

Post a Comment