Bi orileede Naijiria ṣe n ṣe ayẹyẹ ayajọ ọdun kẹrinlelọgota to gba ominira, ajọ to n pin ina mọnamọna ẹka ti Ibadan, Ibadan Electricity Distribution Company (IBEDC), ti ke si awọn ọmọ orileede yii lati jawọ ninu iwa jiji ina ijọba lo.
Ileeṣẹ naa fi da awọn onibara wọn loju pe awọn ko yẹsẹ ninu ipinnu awọn nipa oniruuru ọna ti idagbasoke yoo fi ba orileede Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti adele alakoso agba fun ileeṣẹ ọhun, Ẹnjinia Francis Agoha, fi sita lati ki awọn ọmọ Naijiria ku oriire ayajọ ominira lo ti ke si wọn lati mu iwa ododo, iṣẹ aṣekara ati jijẹ ọmọ orileede yii tootọ lọkunkundun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ina mọnamọna jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹka ti ọrọ-aje orileede rọgbọku le, ileeṣẹ IBEDC ko si kaarẹ ninuu ojuṣe rẹ nipa ipese ina fawọn onibaara rẹ loorekoore.
Latari idi eyi, Ẹnjinia Agoha ke si awọn onibaara wọn lati yago fun iwa titọwọ bọ mita loju ati mimu ina wọle lọna aitọ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ki i ṣe pe iwa naa ni ijiya ẹwọn ọdun mẹta nikan o tun maa n ṣakoba fun ipese ina, o si jẹ iwa ti ko dara si orileede ẹni, bẹẹ lo si lewu fun ẹmi ati dukia.
O parọwa si awọn araalu lati tete maa taṣiri ẹnikẹni to ba n hu iru iwa buruku bẹẹ, ki wọn ma baa ṣe idiwọ fun ipese ina fun awọn to ku.
Ileeṣẹ naa sọ pe awọn onibaara awọn le ra ina mọnamọna lati ori awọn ikanni ayelujara wọnyii: IBEDCPAY app, IRecharge, Quickteller, Payarena, Jumia, Watu, Buypower, ati lori ATM banki.
Awọn onibaara si le kan si wọn nipasẹ customercare@ibedc.com tabi ki wọn pe nọmba yii: 07001239999.
No comments:
Post a Comment